Awọn agbebọn pa adajọ sinu kootu to ti n gbọ ẹjọ lọwọ

Monisọla Saka

Ọjọ buruku eṣu gbomi mu ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Keji, ọdun yii, jẹ fawọn eeyan agbegbe Ejemekwuru atawọn idile Ọgbẹni Ugboma lapapọ.

Eyi ko sẹyin bi awọn agbebọn tẹnikẹni ko ti i le sọ ibi ti wọn ti wa ati idi ti wọn tori ẹ pa Nnaemeka Ugboma, ti i ṣe adajọ kootu ibilẹ to wa niluu Ejemekwuru, nijọba ibilẹ Oguta, nipinlẹ Imo. Lasiko ti ọkunrin naa wa lori aga idajọ to n gbọ ẹjọ lọwọ ni wọn wọnu kootu, ti wọn si yinbọn pa a.

Ọkada ni wọn lawọn agbebọn naa gbe wa, girigiri wọn ati bi wọn ṣe pa adajọ naa lo mu ki idarudapọ bẹ silẹ layiika ile-ẹjọ ọhun, eto igbẹjọ to n lọ lọwọ lasiko igba naa si fori ṣanpọn, niṣe ni kaluku awọn agbẹjọro, oṣiṣẹ kootu, atawọn ero ti wọn wa nibi igbẹjọ naa sa asala fun ẹmi wọn.

Ibẹrubojo ati idarudapọ ti iku ọkunrin adajọ ti wọn lo jẹ ọmọ bibi ilu Nnebukwu, ijọba ibilẹ Oguta, nipinlẹ naa, da silẹ ninu ilu Ejemekwuru, ni wọn lo ṣokunfa bi awọn araalu ṣe n sa kuro nile wọn, ti kaluku si n fori le ibi to ba ri, ki ijamba ma baa ṣe wọn.

Ẹnikan to bawọn oniroyin sọrọ ṣalaye pe, “Ọdun 1991 ni ọkunrin adajọ yii ṣetan nileewe giga to ti kẹkọọ imọ nipa ofin. Inu kootu to ti n gbẹjọ lọwọ ni wọn pa a si. Ọkada lawọn agbebọn ti wọn pa a gun wa, inu ile-ẹjọ ni wọn wọ lọ taara bi wọn ṣe de. Bo ṣe di pe wọn wọ ọ jade sita niyẹn, loju-ẹsẹ nibẹ ni wọn si yinbọn pa a. Bi wọn ṣe pa a tan ni wọn ṣina si ọkada wọn ti wọn lọ. Gbogbo awọn ero kootu, titi kan awọn oṣiṣẹ kootu pata, ni wọn fẹsẹ fẹ ẹ, ni gbogbo igba ti oku ọkunrin naa ṣi wa ninu agbara ẹjẹ ara ẹ nita gbangba. Gbogbo ẹ lo tilẹ daru mọ eeyan loju, tori ko sẹni to mọ idi ti wọn fi pa a. Ọmọ bibi ilu Nnebukwu, nijọba ibilẹ Oguta, wa nibi naa ni oloogbe”.

Ninu ọrọ tiẹ, alaga ẹgbẹ awọn lọọya niluu Owerri, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Imo, Ugochukwu Allinor, toun naa fidi iṣẹlẹ iku ọkan lara wọn ọhun mulẹ sọ pe ẹgbẹ awọn agbẹjọro ẹka ti ipinlẹ Imo yoo ba awọn araalu sọrọ lori igbesẹ to ba yẹ ni gbigbe lori iṣẹlẹ naa laipẹ.

Leave a Reply