Awọn agbebọn tun ji ọmọ China mi-in l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

 

Awọn agbebọn ti ji ọmọ ilẹ China kan to jẹ kọngila gbe niluu Igbemọ-Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun, bẹẹ ni ko sẹni to mọ ibi tọkunrin ọhun wa di akoko yii.

Lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee os yii, ni ALAROYE gbọ pe awọn agbebọn ọhun kọ lu ọkunrin naa to jẹ alakooso awọn to n ṣe oju ọna Ilupeju-Ekiti si Ire-Ekiti, Igbemọ-Ekiti ati Ijan-Ekiti.

A gbọ pe lasiko ti ọkunrin naa n lọ loju titi marosẹ pẹlu mọto Toyota Hilux lawọn eeyan naa deede bẹ si titi, ti wọn si fibọn halẹ ki wọn too gbe ọkunrin oyinbo naa lọ.

Eyi jẹ igba keji ti iru iṣẹlẹ naa yoo ṣẹlẹ si awọn ọmọ China to n ṣe titi l’Ekiti nitori loṣu kọkanla, ọdun to kọja, ni iru ẹ waye loju ọna Ado-Ekiti si Iyin-Ekiti, nibi tawọn agbebọn naa ti pa ọlọpaa kan ki wọn too gbe kọngila lọ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ tuntun yii, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe ikọ ọlọpaa Rapid Response Squad ti bẹ lu gbogbo igbo agbegbe naa, wọn si n sa gbogbo ipa wọn lati gba ẹni ti wọn ji gbe silẹ pada lalaafia.

Leave a Reply