Awọn agbebọn tun ti ji awọn agbẹ mẹta mi-in gbe ninu oko wọn

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ sifu difẹnsi, ‘Nigeria Security And Civil Defence Corps’, (NSCDC) ẹka tilu Dutsinma, nipinlẹ Katsina, ti bẹrẹ igbesẹ lati gba awọn agbẹ mẹta kan tawọn agbebọn lọọ ji gbe ninu ọkọ wọn lakooko ti wọn n ṣiṣẹ lọwọ ninu ọgba ileewe  ‘Federal University Dutsinma’, nipinlẹ Katsina. L’Ojọruu, Wesidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla yii, silẹ.

ALAROYE gbọ pe inu oko, nibi tawọn agbẹ mẹfa kan ti n ṣiṣẹ lọwọ ni wọn wa tawọn agbebọn ọhun ti wọn pọ daadaa fi ya wọnu ọgba ọhun pẹlu ọkada mẹwaa, ti wọn si ko oniruuru ohun ija oloro lọwọ. Gbau-gbau ti wọn n yinbọn ọwọ wọn soke lo mu kawọn agbẹ ohun ti wọn n ṣiṣẹ jẹẹjẹ wọn fi bẹrẹ si i sa asala fun ẹmi wọn. Nibi ti wọn ti n sa kaakiri inu igbo ni meta lara wọn ti ko sọwọ awọn agbegbọn naa, ni wọn ba ki wọn mọle, wọn ji wọn gbe sa lọ, ṣugbọn ori ko awọn ẹlẹgbẹ wọn yooku yọ lọwọ ewu nitori pe niṣe lawọn oṣiṣẹ ajọ NSCDC kan to wa nitosi koju awọn agbebọn naa, ti wọn si gba wọn silẹ.

Alukoro ajọ naa, nipinlẹ Katsina, Ọgbẹni Buhari Hamisu, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, ni olu ileeṣẹ wọn kan to wa nipinlẹ naa sọ pe awọn ọmọọṣẹ oun kan ti wọn rin sasiko iṣẹlẹ ọhun lo gba awọn agbẹ mẹta yooku silẹ lọwọ awọn agbebọn naa, ṣugbọn awọn ṣi n ṣiṣẹ lọwọ lati gba awọn mẹta ti wọn ti kọkọ ji gbe sa lọ silẹ bayii.

O ni, ‘‘A ko ni i fọrọ naa ṣe pe awa la wa nibẹ rara, a maa ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn agbofinro gbogbo kọwọ le tẹ awọn ọdaran ọhun. Awọn mẹta la ri gba silẹ lọwọ awọn agbebọn naa, awọn mẹta yooku wa lọdọ awọn agbebọn naa bayii. Lara Obinrin ni gbogbo awọn ta a ri gba silẹ, nigba tawọn to wa lahaamọ awọn agbebọn ọhun jẹ ọkunrin meji ati ọmọde kan. A maa too fọwọ ofin mu gbogbo wọn pata, ta a si maa gba awọn agbẹ ọhun silẹ ninu igbekun ti wọn fi wọn si laipẹ yii.

Leave a Reply