Iroyin to jade bayii ni pe awọn agbebọn kan ti ya wọle Sunday Adeyẹmọ, ti wọn n pe ni Sunday Igboho, ni ọganjọ oni Ọjọbọ, Ojo Alamisi yii, ti wọn si da ibọn bole gidigidi. Alukoro fun Sunday Igboho ati awọn igbimo ajijagbara re, Ọlayọmi koiki lo kede ọrọ naa sita.
Koiki sọ pe ile Igboho to wa ni agbegbe Soka ni Ibadan lawọn agbebọn naa wa, o ni ohun to is daju ni pe ṣọja ni wọn, nitori aṣọ ṣọja ni wọn wọ. Gbogbo ara ogiri ile naa ati moto ni wọn fi ibọn ja, ti awọn ọta ibọn ati ẹjẹ si wa lawọn ibomi-iin ninu ile naa.
Ko si Igboho funra ẹ nile nibẹ, ṣugbọn awọn araadugbo ni awọn n gbọ iro ibọn nile naa fun ọpọ igba, awọn ko si mọ awọn ti wọn n yinbon naa, afi awọn araale nikan ni wọn le sọ. Awọn kan ninu awọn eeyan ile naa sọ pe awọn ti wọn wa sibẹ n sọ oriṣiriṣi ede bii Faranse ati Hausa, bẹe ni wọn wọ aṣọ ologun.
Iroyin naa fi kun un pe wọn pa awọn eeyan nibẹ pẹlu, iye awọn ti wọn pa abt orukọ wọn ko ti i jade. Ẹkun rẹre iroyin naa n bọ laipe rara.