Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Egbinrin ọtẹ, bi a ṣe n pa ọkan ni omiiran n ru ni ọrọ ijinigbe da ni Kwara bayii pẹlu bi awọn ajinigbe ọhun ṣe tun ji ọkunrin kan, Akeem Aminu, ti wọn tun sẹku pa Aro Rasak, lasiko ti wọn se akọlu si ileetura kan ti orukọ rẹ n jẹ Zulu Abẹjẹ, to wa niluu Madala, Opopona Alapa, nipinlẹ Kwara.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi lede lọjọ Aiku, Sannde, opin ọsẹ yii, lo ti sọ pe awọn agbebọn ti wọn to mẹsan-an niye ti wọn dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro ninu aṣọ ọmọ ologun, ni wọn ya bo iletura ọhun ni alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ti wọn si gbero lati ji ẹni to ni ileetura naa ti orukọ rẹ n jẹ Zulu gbe lọ. Ṣugbọn ori ko ọkunrin naa yọ. Nigba ti wọn bẹrẹ si i rọjo ibọn niwaju ileetura ọhun ni ibọn ba Aro Rasak, to jẹ ọmọ agbegbe Ọlọjẹ, n’Ilọrin, to si ku loju-ẹsẹ. Ajayi tẹsiwaju pe lẹyin ti wọn sẹku pa Aro tan ni wọn ji Akeem Aminu, ọmọ agboole Anifowoshe, gbe lọ.
Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Tuesday Assayamo, ti waa mu un da awọn eeyan agbegbe naa loju pe awọn yoo doola ẹmi ẹni ti wọn ji gbe ọhun laipẹ. O ni awọn agbofinro pẹlu ajọṣepọ awọn fijilante ti wa ni gbogbo inu igbo to yi agbegbe naa ka. Bakan naa lo parọwa sawọn araalu ti wọn n gbero lati ṣe iwọde ifẹhonuhan lati tọwọ ọmọ wọn bọṣọ, ki wọn ma tẹ ofin loju, eyikeyii to ba tẹ ofin loju yoo foju wina ofin, nitori awọn ẹsọ alaabo ti yi gbogbo ilu naa ka, ti wọn yoo si doola ẹmi ẹni ti wọn ji gbe.