Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Inu ibanujẹ ni mọlẹbi oniṣowo pataki kan lagbegbe Alagbado, niluu Ilọrin, Iya Misitura, wa bayii. Awọn agbebọn lo lọọ ka a mọlẹ, wọn yinbọn pa ọmọkunrin rẹ, AbdulGaniy Musa, wọn tun gbe ọmọbinrin rẹ, Misitura, lọ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila oru mọju ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa yii, ni awọn agbebọn naa lọọ ka wọn mọle, ṣugbọn awọn eeyan naa ko ṣilẹkun fun wọn, ni nnkan bii aago mẹta ni wọn too ri ilẹkun ja wọle. Lati oju ferese ni wọn ti yinbọn pa Musa, nigba ti wọn wọle tan ti wọn ko ri Alaaja ni wọn ba gbe Misitura to jẹ ọmọ rẹ lọ.
Lara awọn mọlẹbi to ba ALAROYE sọrọ nibi eto isinku ọmọkunrin naa laaarọ ọjọ Ẹti sọ pe awọn agbebọn naa ti pe, ti wọn si n beere miliọnu mẹwaa Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ. Wọn ni ki awọn mọlẹbi ọmọ yii tete sanwo naa kiakia.
Wọn tẹsiwaju pe ede Fulani ni awọn agbebọn naa n sọ.
Tẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja ni awọn agbebọn kan ṣakọlu sile aafaa kan ti wọn n pe ni Aribidesi, lagbegbe ti ko jinna si Alagbado, wọn du u bii ẹran, wọn tun ko awọn ọmọ rẹ meji lọ ki ori too ko awọn ọmọ naa yọ. Eyi lo mu ki awọn kan maa sọ pe awọn kan maa sọ pe agbebọn to ṣiṣẹ Aribidesi lo wa nidii eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ bayii. Awọn mọlẹbi ni awọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti.