Awọn agbofinro fi mọto kọlu iya agbalagba ni Berger, ni wọn ba sa lọ

Faith Adebọla

Bi a ba yọwọ ti pe oniṣẹ ara l’Ọlọrun kuro, ko daju pe mama agbalagba kan tawọn oṣiṣẹ ikọ amuṣẹya to mu awọn arufin irinna l’Ekoo ti wọn n pe ni Task Force, kọ lu lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹwaa yii yoo ru u la, tori bi wọn ṣe fi mọto wọn kọlu obinrin naa ni mọto ọhun tun gori rẹ kọja, o si fara pa yanna-yanna.

Nnkan bii aago meji ọsan ọjọ naa niṣẹlẹ ibanujẹ yii waye, nibudokọ ti w wọn ti n wọ ọkọ Ibadan ati Abẹokuta, lẹgbẹ titi marosẹ Eko si Ibadan, ni Berger.

Wọn lawọn agbofinro naa wọṣọ idanimọ wọn, ṣugbọn bọọsi akero kan ni wọn gbe wa.

Awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn sọ f’ALAROYE pe ọkọ kan to tẹ siloo bii ẹni fẹẹ gbero leti titi naa lawọn agbofinro ti wọn ti lugọ pamọ sitosi fẹẹ mu, ere buruku ni wọn sa ki wọn le fi ọkọ wọn mu omi-in mọlẹ, ṣugbọn niṣe ni wọn yiwọ mọ mama agbalagba tẹnikan o morukọ ẹ yii, wọn fi mọto kọlu u, wọn tun gori kọja, tori gbara tiṣẹlẹ naa ti waye ni wọn ti ṣiyan-an ti wọn o si duro gbọbẹ, boya nitori kawọn ero to wa nibudokọ ma ba a ya bo wọn.

Nigba t’ALAROYE debi iṣẹlẹ naa, a ri mama ọhun ninu ọgbara ẹjẹ, awọ ori ẹ bi bo borokoto lapakan, bẹẹ lo fi gbogbo ara ṣeṣe gidigidi, aṣọ ọrun ẹ si ti di akisa latari bi mọto naa ṣe lọ ọ mọlẹ.

Awọn ẹsọ oju popo Road Safety to sare debi iṣẹlẹ naa lo ṣeto ọkọ agboku-u-gbalaaye wọn, ti wọn si gbe mama ọhun lọ sọsibitu, boya awọn dokita ṣi le doola ẹmi ẹ.

Ọpọ awọn onimọto, atawọn ero to wa nibi iṣẹlẹ ọhun ni wọn fi itara sọrọ nipa iwakiwa awọn oṣiṣẹ Task Force naa, ati bi wọn ṣe maa n fooro ẹmi awọn ero ati onimọto nigbagbogbo.

Bẹẹ lawọn eeyan bẹnu atẹ lu bawọn agbofinro ṣe maa n haaya mọto ero tabi ọkọ adani lati fi i ṣiṣẹ, eyi to mu ko ṣoro lati da ojulowo oṣiṣẹ ijọba atawọn fawọraja ti wọn n dibọn bii agbofinro mọ.

ALAROYE pe alaga ikọ Task Force naa, CSP Sọla Jẹjẹloye lori aago lati wadii nipa iṣẹlẹ yii, o loun ti beere boya awọn ọmọọṣẹ oun lo lọọ ṣiṣẹ ni Berger laaarọ ọjọ naa, ṣugbọn awọn toun ṣi ba sọrọ lawọn o mọ nipa ijamba to waye ọhun. O loun maa tubọ ṣewadii siwaju si i, o si tun sọ pe oun ti kilọ gidigidi fawọn oṣiṣẹ wọn lati maṣe lo ọkọ m-in yatọ sọkọ tijọba pese lẹnu iṣẹ wọn, bẹẹ ni ko tọna lati sare asapajude nitori ki wọn le mu arufin, tabi ki wọn wu awọn mi-in lewu lẹnu iṣẹ wọn.

Leave a Reply