Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ti wọn ti wọn ko awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio Amuludun, n’Ibadan, ni papamọra, ti wọn si fipa gbajọba ileeṣẹ naa fun bii wakati kan, ọwọ awọn agbofinro ti tẹ marun-un ninu awọn janduku eeyan naa.
Amuludun 99.1 FM, n’Ibadan, to jẹ ẹka ileeṣẹ redio ijọba apapọ ta a mọ si Premier FM, lo padanu ileeṣẹ naa sọwọ awọn gende ọkunrin rẹpẹtẹ kan bayii ti wọn deede ya wọ ileeṣẹ naa tijatija.
Awọn alakatakiti eeyan ọhun, ti wọn ni wọn n ja fun ominira ilẹ Oodua, la gbọ pe wọn ya wọ ileeṣẹ Redio Amuludun to wa ni Mọniya, n’Ibadan, ni nnkan bii aago mẹfa idaji ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, pẹlu oriṣiiriṣii oogun abẹnugọngọ.
Pẹlu igbe, “Yoruba Nation” ta a gbọ pe wọn n ke nigba ti wọn n ya wọ inu ọgba naa, ko gba awọn alakatakiti eeyan ọhun to iṣẹju marun-un ti wọn fi gbakoso ileeṣẹ nla naa lẹyin ti wọn ti doju ija kọ awọn oṣiṣẹ ibẹ pẹlu nnkan agbara ibilẹ ti wọn fi dihamọra, ti awọn onitọhun si ti sa asala fun ẹmi wọn.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nnkan bii wakati kan lawọn eeyan naa fi sọrọ daradara lori redio lẹyin ti wọn ti gbakoso ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ọhun, ko si sohun meji ti wọn n sọ fun gbogbo aye lori afẹfẹ ju ọrọ Yoruba Nation lọ, wọn ni ọrọ ominira Yoruba ti bọ si i na, ko sohun tẹnikẹni le ṣe si i.
Oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun kan fidi ẹ mulẹ fakọroyin wa pe, “Niṣe ni wọn gba foonu ọwọ gbogbo awọn ti wọn ba lẹnu iṣẹ lasiko yẹn, ti wọn si bẹrẹ si i sọrọ lori afẹfẹ bo ṣe wu wọn.
“Nigbẹyin, gbẹyin, awọn kan pada fi ohun to n ṣẹlẹ to awọn agbofinro leti. Nigba ti awọn Operation Burst si de, awọn eeyan yii bẹrẹ si i pariwo tan-tan-an-tan lori redio, wọn n pe awọn to ran wọn niṣẹ pe ki wọn maa bọ waa gba awọn silẹ o, wọn ti waa ko ibọn ka awọn mọ o.
Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, Ọga agba ileeṣẹ redio Amuludun, Ọgbẹni Stephen Agbaje, sọ sọ pe oju oorun ni diẹ ninu awọn oṣiṣẹ awọn ṣi wa nigba ti awọn alejo ọran naa ṣigun de, o si jọ pe wọn ti fara pamọ sibi kan ko too di aago mẹfa idaji ti wọn pitu ọwọ wọn naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn ikọ ajijagbara kan wa lalẹ ana, wọn si gbakoso ileeṣẹ wa. Oju oorun lawọn kan ninu awọn oṣiṣẹ wa ṣi wa lasiko yẹn paapaa.
“Titi di ba a ṣe n sọrọ yii, a o ti i ri awọn kan ninu awọn oṣiṣẹ wa. Ṣugbọn awọn agbofinro ti gbakoso ileeṣẹ yii pada, eto aabo ti duro deede, ohun gbogbo si ti n lọ bo ṣe yẹ”.
O fìdi ẹ mulẹ pe marun-un ninu awọn afurasi ọdaran naa lọwọ awọn eleto aabo ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Operation Burst ti tẹ ninu awọn eeyan naa bayii.
Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii lawọn agbofinro ṣi n ṣewadii lori iṣẹlẹ yìí.