Awọn ajinigbe yinbọn pa Musa, nitori ti ko jẹ ki wọn jiyawo ẹ gbe lọ

Monisọla Saka

Awọn ajinigbe ti da ẹmi ọkunrin kan, Musa Abari Kusaki, legbodo, lasiko ti wọn ṣakọlu sile ẹ to wa labule Kasada, agbegbe Kuje, niluu Abuja, ti wọn si ji iyawo ẹ atawọn marun-un mi-in gbe sa lọ.

ALAROYE gbọ pe awọn agbebọn ti wọn pọ niye, ti wọn dihamọra ogun pẹlu ibọn alayinyipo AK-47, ni wọn ya wọ abule wọn ni nnkan bii aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, wọn si bẹrẹ si i yinbọn leralera. Awọn olugbe agbegbe naa ni tipatikuuku lawọn agbebọn naa fi n wọnu ile awọn.

Ifẹ ati aajo iyawo lo pa oloogbe yii, lasiko to n di awọn agbebọn naa lọwọ lati ma ṣe ji iyawo rẹ gbe sa lọ ni wọn ti yinbọn fun un lọgangan igbaaya, oju-ẹsẹ lo mu idi lọ silẹ, o si ku patapata.

Lẹyin eyi lawọn agbebọn yii tun pada ji Arabinrin Hulaira, ti i ṣe iyawo oloogbe lọ, lai wo ti pe awọn ti pa ọkọ ẹ. Bi wọn ṣe ji iyaale ile ọhun gbe tan ni wọn kọja sawọn ile alaamuleti wọn, ti wọn si tun ji awọn marun-un mi-in gbe, lẹyin eyi ni wọn pada sinu igbo ti wọn ti wa.

Ọkan ninu awọn ọrẹ oloogbe lo tufọ iku ọkunrin naa sori ayelujara (Facebook). Latigba naa ni tẹbitara, ọrẹ ati ojulumọ ti n kọ ọrọ ibanikẹdun ati arò nipa eeyan wọn to ku lasiko to fẹẹ doola iyawo ẹ sabẹ fọto rẹ. Wọn ni ibanujẹ nla ni iku ẹ jẹ fawọn, bẹẹ lo wọ awọn lara, to si dun awọn gidigidi.

 

Leave a Reply