Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Nnkan daru patapata nileewe ti wọn ti n kọ nipa eto ilera nipinlẹ Ekiti, iyẹn College of Health and Technology, nigba ti bii ọgọrun-un awọn akẹkọọ ileewe naa daku lọ gbọnrangandan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nitori oorun kẹmika ti wọn fin sileewe naa ti awọn akẹkọọ ohun fa simu. Eyi lo mu ki awọn akẹkọọ naa bẹrẹ ija, ti wọn si ba ọpọ nnkan jẹ nileewe naa.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ naa waye nigba ti ileeṣẹ panapana waa fin ọgba ileewe naa.
Lasiko ti awọn akẹkọọ naa jokoo lati ṣedanwo ni wọn ri i pe niṣe ni bii ọgọrun ninu wọn ti daku lọ, oju-ẹsẹ ni wọn si sare gbe wọn lọ si ọsibitu ijọba to wa ni Ijereo-Ekiti. A gbọ pe ọpọ awọn akẹkọọ tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ni wọn ni aisan seeemi-seeemi ti awọn oloyinbo n pe ni (Athsma), eyi to lewu fun iru ẹni to ba ni aisan bẹẹ lati fa awọn kẹmika tabi oorun to ba ti le ju simu.
Oorun yii lawọn akẹkọọ naa fa simu to ṣakoba fun ilera wọn.
Ibinu ni iṣẹlẹ naa lawọn akẹkọọ yooku fi ya lọ si ọọfiisi awọn alaṣẹ ileewe naa, ti wọn si beere ohun to fa wahala naa. Wọn ko tiẹ duro gbesi ti wọn fi bẹrẹ si i ba oriṣiiriṣii nnkan jẹ nileewe naa. Bi wọn ṣe n ba awọn yara ikẹkọọ jẹ ni wọn n ba mọto atawọn nnkan olowo iyebiye mi-in jẹ, o si pẹ diẹ ki wọn too pana wahala naa.
Kọmiṣanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ekiti, Dokita Banji Filani, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni loootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn awọn ti ṣe amojuto to yẹ, alaafia si ti n pada sileewe naa. Kọmiṣanna ni awọn akẹkọọ bii mẹrinlelọgọta ni wọn ti gbadun, ti wọn ti pada sile, beẹ ni awọn mẹrinlelọgbọn ṣi wa ni ibi ti wọn ti n gba itọju. O fi kun un pe awọn ti pe awọn eleto ilera mọra lati le fun awọn akẹkọọ naa ni itọju to peye.
Nigba to n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ, Filani ni ọga ileewe naa pe oun lati ṣalaye pe awọn ileeṣẹ pana pana fẹẹ wa fi kẹmika si ileewe naa. Wọn si wa loooto, wọn waa fin in. Afi bi wọn ṣe fin in tan ti wahala ṣẹlẹ. Oorun kẹmika naa lo gbodi lara awọn akẹkọọ kan ti wọn fi daku, ti aọn si sare gbe wọn lọ si osibitu ijọba to wa ni Ijero-Ekiti.
O fi kun un pe wọn ti mu diẹ ninu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana to waa fin kẹmika naa lati wadii ọrọ lẹnu wọn. Bẹẹ lo sọ pe ara awọn akẹkọọ naa ti n ya, ki awọn araalu fọkan balẹ.