Stephen Ajagbe, Ilorin
Awọn akẹkọọ nipinlẹ Kwara l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, fẹhonu han, pe awọn ko fara mọ ọn bi tako bijọba ṣi ṣe ti ileewe awọn pa, wọn ni bawọn ṣe n jokoo sile ti su awọn.
Gbogbo oju titi ni wọn gba ti wọn si n kọrin ifẹhonu han titi de abawọle ile ijọba. Oriṣiiriṣii akọle ni wọn gbe lọwọ ti wọn si kesi ijọba lati ṣi awọn ileewe ni kiakia.
Ohun ti wọn n sọ ni pe bi ijọba ba le ṣi awọn papakọ ofurufu, ileejọsin ati ọja, ko sohun to ni ki wọn ma ṣi ileewe.
Ṣe lati bii oṣu mẹrin sẹyin nijọba ti gbe awọn ileewe ti, nitori ati dẹkun atankalẹ arun koronafairọọsi. Ọsẹ to kọja ni wọn ṣi awọn ileewe girama kan lati faaye gba awọn akẹkọọ to fẹẹ ṣe idanwo aṣekagba, ti wọn si ni awọnto ku ko gbọdọ ṣilẹkun wọn.