Jamiu Abayọmi
Ile-iwe ijọba apapọ ti Federal University Dutsin-Ma, (FUDMA), to wa nipinlẹ Katsina, ti paṣẹ fawọn akẹkọọ mẹfa ọtọọtọ kan ti wọn lọwọ ninu iku ọkan lara wọn, Abubakar Nasir-Barda, lati jokoo sile wọn bayii lai ni gbedeke ọjọ, ati pe wọn ki i ṣe ọmọ ile-ẹkọ naa mọ lati wakati ọhun lọ.
Alukoro ileewe naa, Malam Habib Aminu-Umar, lo ṣiṣọ loju ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede fawọn oniroyin l’ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹwaa, ti a wa ninu rẹ yii niluu Katsina.
Ṣaaju asiko yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti kede pe awọn akẹkọọ mẹfẹẹfa ti ajere iwa ipaniyan yii ṣi mọ lori ni wọn ti wa lakolo awọn.
Awọn alaṣẹ ileewe naa ti kede lorukọ awọn igbimọ alaṣẹ to ga ju lọ bayii pe, “O jẹ ẹdun ọkan fun gbogbo alaṣẹ, awọn oṣiṣẹ ati gbogbo akẹkọọ inu ọgba yii lati gbọ pe iru iṣẹlẹ ibanujẹ yii ṣẹlẹ si awọn akẹkọọ wa leyii, to gbẹmi ọkan ninu wọn, Abubakar Nasir-Barda, to wa ni ipele keji ni ẹka ti wọn ti n kọ nipa imọ ẹrọ kọmputa lasiko toun atawọn ẹgbẹ rẹ kan n ja nitori akẹkọ-binrin ẹlẹgbẹ wọn.
“Atigba naa ni awọn alaṣẹ ileewe yii ti bẹrẹ igbiyanju lori bi idajọ ododo yoo ṣe ti ibi iṣẹlẹ ibanujẹ naa wa, eyi lo si jẹ ki a ṣe agbekalẹ awọn ikọ lati ṣewadii pataki lori iṣẹlẹ naa, ti wọn yoo si waa jabọ pada fawọn alaṣẹ bi iwadii naa ṣe n tẹsiwaju. Ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa safẹfẹ rere.