Faith Adebọla
“Oju oorun la wa, ko sẹni to reti pe iru nnkan bẹẹ le ṣẹlẹ, ojiji la kan bẹrẹ si i gburo ibọn tau, tau, ti ko si dawọ duro. Iro ibọn naa lo ji gbogbo wa, ẹru ba wa, awọn kan ni ka sa lọ, ṣugbọn a o mọ ibi ti a fẹẹ sa gba, awọn kan sa lọ sinu tọilẹẹti, olukaluku sa lọ, awa meji la ku ninu yara nla ti a n sun si. Bẹẹ ni iro ibọn ti wọn n yin n dun nita, ko dawọ duro rara. Awọn adigunjale la ro pe wọn de.”
Bayii ni Farida Lawali, ọmọ ọdun mẹẹẹdogun, to jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ tawọn janduku agbebọn ji gbe nileewe Government Girls Secondary School, to wa ni Jangebe, nipinlẹ Zamfara, ṣe royin bi iṣẹlẹ buruku naa ṣe ṣẹlẹ. Nnkan bii aago kan oru ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji, to kọja yii, lawọn agbebọn naa ṣakọlu sileewe awọn akẹkọọ-binrin naa, wọn ji ọọdunrun ati mẹtadinlogun gbe lara wọn, wọn si ko wọn wọgbo lọ.
Farida ni niṣe lawọn agbebọn naa da ẹnu ibọn kọ ori wọn, ti wọn si paṣẹ pe ki awọn maa rin niṣo, wọn lawọn maa yinbọn pa ẹnikẹni to ba kọ lati ṣe bawọn ṣe wi.
“Ẹsẹ la fi rin kuro niluu, titi ta a fi de inu igbo. A o riran, inu okunkun la n fẹsẹ rin gba ori okuta kọja, gbogbo wa la bu sẹkun, bi a ṣe n rin lọ la n wa ẹkun mu, ṣugbọn wọn bẹrẹ si i jan idi ibọn mọ wa pe ka dakẹ, nigba tawọn kan o tete dakẹ, wọn fi ibọn lu wọn, wọn la igi mọ awọn mi-in lori.
“O ti rẹ awọn kan ninu wa tori ara wọn o ya tẹlẹ. Awọn agbebọn naa gbe awọn ti ko le rin daadaa ati awọn ti ara wọn o ya si apa wọn. Bẹẹ la n fẹsẹ kọ okuta ati ẹgun ati okun ninu igbo. Mi o ri iru e ri laye mi.”
Akẹkọọ-binrin mi-in, Umma Abubakar, sọ pe, “Nigba ta a de inu igbo, oju kan naa ni wọn ko gbogbo wa si, ibẹ la si wa fun ọjọ mẹrin ta a lo lahaamọ wọn, gbangba ita nibẹ naa la n sun si. Ẹni to ba fẹẹ yagbẹ tabi tọ maa bọ si ẹgbẹ kan, agbebọn kan si maa duro ti i, ṣugbọn gbogbo eeyan maa ri ihooho ẹ.
“Ninu ibẹru la n ṣe gbogbo nnkan, ninu ibẹru la n jẹun, la n yagbẹ, la n sun, tori a o mọ boya a tun le pada sile mọ, a o mọ boya a tun le ri awọn obi wa mọ. Awọn agbebọn naa ni awọn le pa gbogbo wa tinu ba bi awọn.’’
Akẹkọọ-binrin mi-in, Hanainatu Abubakar sọ pe, “Awọn agbebọn naa fi wa ṣẹsin gidi, wọn pe wa lorukọ buruku, wọn bu wa, wọn si halẹ pe awọn maa pa wa danu ni. Ṣugbọn nigba to ya, wọn tun sọ pe ka gbadura fawọn ki awọn le di ọmọ Naijiria rere. Wọn lo wu awọn lati mọ ede Gẹẹsi i sọ, wọn ni ka maa kọ awọn, awọn fẹẹ gbọ oyinbo.
“Nigba kan, awọn kan ti wọn duro ti wa sọ pe awọn maa fipa ba wa sun, ẹni ti ko ba si gba ninu wa, awọn maa yinbọn fun un. Ẹru ba mi gan-an, ṣugbọn olori wọn gbọ, o si kilọ fun wọn pe wọn o gbọdọ ṣe bẹẹ. Irẹsi ni wọn n se fun wa, irẹsi nikan, ko si ata ọbẹ tabi ororo. Ti wọn ba ti bu u fun wa, niṣoju wa ni wọn ṣe maa bu yeepẹ nilẹ, wọn a wọn ọn sori irẹsi naa, wọn aa ni ka maa jẹ ẹ, pe iyọ ni yeepẹ tawọn bu si i yẹn. Nigba ta a kọkọ debẹ, ọpọ ninu wa kọ lati jẹ ẹ, ṣugbọn nigba ti ebi pa wa, ti ko si si ounjẹ mi-in, niṣe la gba kamu, a n jẹ ẹ bẹẹ.”
Hanainatu sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe bo tilẹ jẹ pe oru ni wọn waa ji awọn ko, oun ṣi ranti awọn ọna ti wọn mu awọn gba, oun si le da oju diẹ lara awọn agbebọn naa mọ toun ba ri wọn.