Adewale Adeoye
Nitori bi wọn ṣe lu akẹkọọ ẹgbẹ wọn, Okoli Ahize, pa nitori foonu ti wọn lo ji gbe, ọwọ ti tẹ ẹni ti wọn lo ṣaaju iwa buruku naa, awọn alaṣẹ ileewe naa si ti fa a le ọlọpaa lọwọ lati le ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn nipa iku oloogbe naa.
Alukoro ileewe ọhun, Abiọdun Ọlanrewaju, lo sọrọ ọhun di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ninu ọgba ileewe naa.
O ṣalaye pe inu ọga agba patapata fasiti ọhun, Ọjọgbon Simeon Bamire, ati gbogbo awọn oṣiṣẹ ileewe ọhun pata ko dun rara sohun to ṣẹlẹ naa, ati pe ko yẹ ki awọn akẹkọọ ọhun maa ṣe amulo ofin lati ọwọ ara wọn lati fiya jẹ akẹkọọ ẹgbẹ wọn gẹgẹ bo ṣe waye yii.
Ọlanrewaju ni awọn alaṣẹ ileewe naa ti gbe igbimo oluwadii kan kalẹ lati ṣewadii ijinlẹ, ki wọn si mọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.
Tẹ o ba gbagbe, ilegbee awọn akẹkọọ, iyẹn Awo Hall, ni wọn ti fẹsun kan akẹkọọ naa pe o ji foonu lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu yii, latibẹ ni wọn si ti bẹrẹ si i lu u lalubami. Bi ilẹ ọjọ Tusidee tun ṣe mọ ni wọn gbe e lọ sibomi-in, nibi ti wọn tun ti n lu u titi di ọsan.
Nigba ti wọn ri i pe ẹmi ti fẹẹ bọ lara rẹ ni wọn sare gbe e lọ sileewosan ẹkọṣẹ iṣegun ti ileewe giga naa, iyẹn Ọbafẹmi Awolowọ Teaching Hospital, Ile-Ife, ṣugbọn ọmọkunrin yii ko ti i gba itọju kankan to fi jade laye.
Ipele aṣekagba ni Oloogbe Okoli Ahize to jẹ akẹkọọ ni ẹka imọ ẹrọ wa nileewe naa ki wọn too ṣeku pa a