Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn alaṣẹ ileewe giga Fasiti Ilọrin, ti le akẹkọọ ileewe naa, Salaudeen Waliu Aanuoluwa, to lu tiṣa rẹ, Arabinrin Zakariya, bii aṣọ ofi ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ to kọja, danu nileewe, wọn ni ti ko ba tẹ ẹ lọrun, ko pẹjọ ta ko awọn alaṣẹ ileewe naa laarin ọjọ mejidinlaaadọta pere.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileewe naa, Ọgbẹni Kunle Akọgun, fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lo ti sọ pe Ọga agba ileewe naa, Ọjọgbọn Abdulkarim Agẹ, ti pasẹ pe ki Salaudeen, kuro ninu ọgba fasiti ọhun ni kiakia, ko si ko gbogbo dukia ileewe to ba wa ni akata rẹ kalẹ, to fi mọ kaadi idanimọ rẹ, ṣugbọn ti idajọ yii ko ba tẹ ẹ lọrun, ko pe awọn alaṣẹ ileewe naa lẹjọ laarin ọjọ mejidinlaaadọta pere, ko si salaye idi ti ko fi jẹbi ẹsun ọdaran ti wọn fi kan an.