Iroyin to n jade lati ọdọ awọn alagbara ilu Abuja n sọ bayii pe ọgọọrọ awọn aafaa ni wọn wa lori awọ kaakiri bayii, ti wọn n gbadura kikankikan fun Alaaji Maman Daura, ọkan ninu awọn alatileyin Aarẹ Muhammadu Buhari. Ẹgbọn Buhari ni Daura, ọre tun ni wọn, ṣugbọn asiko ijọba yii lawọn eeyan mọ baba naa ju, nitori oun lo sun mọ olori ijoba Naijiria yii ju lọ.
Mẹta naa ni wọn: Abba kyari, Isa Funtua ati Daura. Ṣugbọn ninu awon mẹtẹẹta yii, Daura lo dagba ju, oun naa lo si sun mọ Buhari ju lọ, nitior tẹgbọn-taburo ni wọn. Laarin awọn mẹta yii ni agbara ijọba Naijiria wa lati bii ọdun marun-un ti Buhari ti gbajọba, nitori awọn gan-an ni wọn n ri i, ti wọn mọ irin rẹ, awọn ni wọn si n dari rẹ sidii ọpọ awọn ohun to n ṣe. Ọrọ naa ti di isọnu nla fun Aarẹ, nitori ọpọ ọmọ Naijiria, ati iyawo oun naa, ni wọn n binu awọn mẹtẹẹta yii, paapaa nigba ti Buhari ati ijọba rẹ ba gbe awọn eto ti ko dara miiran jade.
Afi bi ajakalẹ arun korona yii ṣe bẹrẹ, ti awọn meji deede fo ṣanlẹ ninu wọn ti wọn si ku laarin oṣu meji sira wọn. Abba Kyari lo kọkọ ku, ko si pẹ rara ti Isa Funtua fi tẹ le e. N lo ba ku ẹni kanṣoṣo, iyẹn Daura. Ana ni iroyin jade lojiji pe Daura funra ẹ ti dubulẹ aisan, aisan naa si lagbara, nitori o fara jọ Koro pupọ. Gẹgẹ bi awọn oniroyin Sahara ti wi, lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti gbe Daura gẹgẹ, o di ilu oyinbo, wọn ni apa awọn oniṣegun to wa nibi le ma ka a.
Ṣugbọn sibẹ naa, kinni ọhun ko ti i tẹ Aarẹ ati awọn eeyan rẹ lọrun, wọn ni apa awọn oniṣegun oyinbo lọhun-un naa le ma fẹe ka a, ki awọn tete rọjo adura le e lori lati ibi yii, nitori ariwo ti gbogbo wọn n pa ni pe, ‘Daura ko gbọdọ ku o!’
Oluwa a fun UN ni alaafia, ti o baa n wa rere orile ede yii