Faith Adebọla
Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga, ti i ṣe Alakooso eto iroyin ati ipolongo ibo fun oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Oloye Bọla Ahmed Tinubu, ti fesi si awuyewuye to n lọ nigboro nipa ẹsun ti wọn fi kan gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa pe o ti ṣowo gbigbe egboogi oloro wọlu Amẹrika ri, ati pe wọn da a lẹbi ẹsun naa lọdun 1993, o si padanu owo gegere kan sọwọ ijọba ilẹ Amẹrika tori ẹ, Ọnanuga ni irọ ni, awọn alatako oṣelu lo wa nidii ọrọ yii, o lọrọ to ti ku-regbe ku-regbe ni wọn n lọọ hu sita lati fi tapo s’aṣọ aala ọga oun.
Ọnanuga ṣalaye ọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla yii, nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lori awuyewuye ọhun, l’Abuja.
Ṣe lọjọ Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu yii, lawọn atẹjade rẹpẹtẹ kan bẹrẹ si i fo kiri ori ẹrọ ayelujara, iwe alabala mẹrindinlọgọta kan ti wọn ni kootu United States District Court for the Northern District of Illinois, lorileede Amẹrika, fi lede lọjọ naa lawọn eeyan n ṣe atare ati atagba rẹ, iwe ọhun si da lori bi Bọla Tinubu ṣe jẹbi ẹsun ṣiṣe okoowo ati gbigbe egboogi oloro ti wọn pe ni Heroine, lọdun 1993, wọn lo ko ẹru ofin naa wọlu Amẹrika, ati pe ẹgbẹrun lọna ọtalenirinwo dọla ($460,000) lo padanu rẹ sọwọ ijọba ilẹ Amẹrika lara owo ọja buruku ọhun, ki wọn too paju iwe de lori ẹsun naa.
Ninu alaye rẹ, Bayọ Ọnanuga ni eyi ki i ṣe igba akọkọ tiru ẹsun yii maa jẹ yọ. O lawọn kan ti ru u jade ki ẹgbẹ oṣelu APC too dibo abẹle ti wọn fi fa Tinubu kalẹ, ati pe awọn oniroyin kan ni wọn n jẹ keeefin ọrọ naa ṣi maa ru tuu.
Lẹyin eyi lo ṣalaye bọrọ naa ṣe jẹ, o ni:
“Ibi ti ẹsun yii ti bẹrẹ ni pe ọkunrin ọtẹlẹmuyẹ kan, Kevin Moss, to n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ to n tọpinpin ẹsun l’Amẹrika ti wọn n pe ni FBI, iyẹn Federal Bereau of Intelligence, lo tọpa bọho awọn owo ti ileeṣẹ Tinubu kan l’Amẹrika, Tinubu and Compass Investiment and Finance, tọju sawọn banki meji lọhun-un, First Heritage Bank ati Citi-bank.
“Nigba to di ọjọ kẹwaa, oṣu Ki-in-ni, ọdun 1992, Kevin Moss gbawe aṣẹ ile-ẹjọ lati gbẹsẹ le awọn akaunti Tinubu to wa ni banki mejeeji. Naijiria ni Tinubu wa lasiko yẹn, ọkunrin olutọpinpin naa si pe e lori aago lati beere alaye ẹ nipa awọn owo to wa ninu asunwọn rẹ ọhun, tori owo naa pọ, o to miliọnu kan le nirinwo dọla ($1.4 million). Wọn lawọn meji kan tijọba ilẹ Amẹrika n tanna wodi wọn lori ẹsun ṣiṣe okoowo ati gbigbe egboogi oloro wa lara awọn to fowo pamọ sinu awọn akaunti Tinubu ta a n sọ yii.
“Lẹyin ti Tinubu ti ṣalaye ẹnu ẹ, to si ti fesi awọn ibeere ti wọn bi i, o ni ki lọọya oun l’Amẹrika ba oun gba aṣẹ ile-ẹjọ kijọba le kasẹ kuro lori owo naa.
“Eyi ni wọn n fa lọ fa bọ to fi di ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 1993, nibi ti Tinubu ti tọwọ bọwe adehun pe ki wọn kuku yanju ọrọ naa nitubi-inubi, ki wọn ko ẹjọ kuro ni kootu, ki wọn jọọ jokoo sọ ọ labẹle.
“Adajọ John A. Nordberg tile-ẹjọ giga Ariwa Illinois naa si gba, oun lo kawe adehun ọhun jade lọjọ naa. Asẹyinwa asẹyinbọ, ijọba gbẹsẹ le ẹgbẹrun lọna ọtalenirinwo dọla ($460,000) lara owo naa patapata.
Bayọ Ọnanuga fi kun un pe: “Ko sigba kan ti FBI fẹsun gbigbe egboogi oloro kan Tinubu o, bẹẹ ni ko si kawọ pọnyin rojọ nipa iru nnkan bẹẹ ri. Tinubu ko jẹbi ẹsun kankan, tori ọrọ naa ko dẹjọ nigba yẹn, wọn yanju ẹ lai pe ile-ẹjọ si i ni. Ko sẹni to fofin de Tinubu lati wọ Amẹrika o.
“Igba kan wa lọdun 2003 ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party lọọ hu ọrọ yii jade lati fi re Tinubu bọ nipo gomina, ko ma baa ṣe saa keji l’Ekoo, ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nigba yẹn, Tafa Balogun, ṣewadii pẹlu awọn aṣoju ilẹ Amẹrika nilẹ wa.
Lasiko yii, nnkan bii ọgbọn ọdun sigba yẹn, ti ẹjọ ti ku, ta a ti sinku ẹ, awọn alatako Tinubu ṣi n lọọ ji oku ọhun dide, tori ki wọn le na’ka abuku kan si Tinubu ni wọn ṣe n ṣe bẹẹ,” gẹgẹ bo ṣe wi.