Awọn apaniṣowo yọ oju ọmọ ọdun ọdun mejila lọ

Monisọla Saka

Epe rabandẹ rabandẹ ni gbogbo awọn to gbọ nipa bi awọn apaniṣowo ṣe da ọmọkuntin kan dubulẹ, ti wọn si yọ oju rẹ lọ niluu Kafin-Madaki, nijọba ibilẹ Ganjuwa, nipinlẹ Bauchi, wọn ni wọn fẹẹ fi ṣoogun owo ni.

A gbọ pe awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lati mu awọn to ṣiṣẹ buruku naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ahmed Mohammed Wakil, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun yii, sọ pe, ‘‘Almajiri, iyẹn awọn ọmọ ile-kewu ti wọn maa n fẹsẹ gbalẹ, ti wọn maa n tọrọ baara kiri lati ipinlẹ Kano ni Najim Hussaini ti wọn yọ oju ẹ yii.

Alukoro ọlọpaa naa lawọn ọkunrin meji kan ti ko sẹni to mọ wọn ni wọn gbe ọkada, ti wọn tan ọmọdekunrin ọhun lọ si agbegbe kan to maa n da paroparo labule naa, ti wọn si yọ oju ọtun ọmọ kekere ọhun, lẹyin naa ni wọn fi i silẹ lati maa japoro ninu agbara ẹjẹ nibẹ.

‘‘Ọmọdekunrin ọhun, Najim Hussaini, ọmọ ọdun mejila (12), jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kano, to si n lọ si ile-kewu niluu Kafin-Madaki, la gbọ pe ko ti i lo to ọdun kan labule ọhun ti iṣẹlẹ buburu naafi ṣẹlẹ si i lọjọ kẹsan-an, oṣu Kejila, ọdun yii, ni nnkan bii aago meji oru lagbegbe Unguwar Yamma, ti ko fi bẹẹ jinna si ileewe tọmọ naa ti n kọ ẹkọ kewu ni Tsangaya.

“Awọn ọkunrin meji kan ni wọn sọ pe wọn gbe ọkada Bajaj wa, ti wọn si tan ọmọ naa lọ si ile kan ti ko fi bẹẹ jinna sile-kewu wọn, wọn ni ko ba awọn pe obinrin kan wa.

Ojiji ni wọn ki ọmọ yii mọlẹ, ti wọn si fi ọkada wọn gbe e lọ sibi kan to saaba maa n da nipẹkun abule ọhun, lẹgbẹẹ igbo ni wọn paaki si, lẹyin ti wọn wo ọtun wo osi ti ko sẹnikẹni ni arọwọto ni wọn fagidi yọ oju ọtun ọmọ naa, ti wọn si fi i silẹ lati maa jẹrora ninu agbara ẹjẹ ninu igbo nibẹ”.

Ko pẹ pupọ ni wọn lọmọ naa rapala jade sibi tawọn ẹgbẹ ẹ ti ri i, ti wọn fi mu un lọọ ba aafaa to n kọ wọn ni kewu.

Ni kete ti wọn fi ọrọ naa to wọn leti lagọọ ọlọpaa Ganjuwa, ni wọn ti gbe ọmọ naa lọ sileewosan ẹkọṣẹ iṣegun Abubakar Tafawa Balewa, ni Bauchi.

“Kọmiṣanna Alhassan, ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ latimọ ohun to ṣokunfa bi wọn ṣe yọ oju ọmọ ọdun mejila naa. O waa rọ awọn eeyan lati maa ṣọ ara wọn ati ayika wọn nigba gbogbo, ki wọn si fẹjọ ohunkohun to ba ṣajeji tabi mu ifura dani lagbegbe wọn sun awọn ọlọpaa.

Leave a Reply