Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn eekan ninu ọmọ ilu Iṣẹyin, nipinlẹ Ọyọ, ti ta ko bi awọn afọbajẹ ilu naa ṣe fẹẹ yan ọba tuntun lọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn (28) yii, ni wọn kegbajare naa, wọn ni igbesẹ ti awọn afọbajẹ ọhun fẹẹ gbe ta ko aṣa Yoruba.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lẹyin ipapoda ọba naa lawọn afọbajẹ beere ẹni ti ipo ọba tuntun kan lọwọ Ifa, ti Ifa si tọka onitọhun fun wọn.
Ṣugbọn ọmọ ilu ọhun kan to mọ bi gbogbo ọrọ naa ṣe n lọ sọ pe inu ọkan ninu awọn afọbajẹ naa ko dun si ẹni ti Ifa mu ọhun, n lo ba ṣeto pe ki wọn da eto ọhun ru, ki wọn si bẹrẹ igbesẹ tuntun.
Ẹni naa, to ni ka forukọ b’oun laṣiiri ṣalaye siwaju pe afọbajẹ ta a wi yii ti gba abẹtẹlẹ lọwọ ọkan ninu awọn ọmọ oye to fẹẹ jọba, o si pin ẹgbẹrun lọna ẹdẹgbẹta Naira (₦500,000) ninu owo naa fawọn afọbajẹ lati dibo yan ẹni to fẹ.
Wọn waa rọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lati wa nnkan ṣe lori ọrọ yiiBẹẹ ni wọn tun gba awọn afọbajẹ niyanju lati fi ibẹru Ọlọrun yanju ọrọ ọba ilu naa to wa niwaju wọn.
Ọmọ Isẹyin mi-in ti oun naa ko fẹ ka darukọ oun fidi ẹ mulẹ pe ọna ti awọn afọbajẹ fẹẹ gba yan ọba tuntun yii
lewu fun ilu Isẹyin, nitori iru ilana awuruju bayii ti wọn fi dibo yan Asẹyin to waja niyẹn, iyẹn lo si ṣokunfa bi ọba naa ko ṣe pẹ lori itẹ, nitori inu awọn alalẹ ko dun si ilana yii.
O ni, “bawo lẹ ṣe maa dibo yan ọba nilẹ Yoruba, paapaa niluu Iṣẹyin. Iru ọba bẹẹ le waja laarin ọjọ meje. Wọn ti fun awọn afọbajẹ labẹtẹlẹ lati dibo yan ẹnikan, eyi ko si gbọdọ waye.”
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹrinlelogun (24), oṣu Keje, ọdun 2022, l’Aṣẹyin tilu Isẹyin, Ọba Abdulganiyu Salawudeen, waja lẹyin aisan ranpẹ.