Aderounmu Kazeem
Niluu Ajiran nijọba ibilẹ Eti Ọsa l’Ekoo lawọn eeyan kan ti n binu o, ẹni ti wọn si n binu si ko ju kabiyesi wọn lọ, Ọba Tijani Akinloye, Ojomu tiluu Ajiran.
Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Yẹkinni Wasiu lo duro gẹgẹ bi agbẹnusọ fawọn eeyan to n binu yii. Ẹsun ti wọn si fi kan Ọba alaye naa ni pe gbogbo ohun to jẹ ogun ibi awọn pata lo ti ta tan, ti ohun idagbasoke kan bayii ko si ninu ilu naa.
Wọn ni ko si ileewe kan to jẹ ojulowo, ọsibitu naa ko si atawọn ohun amayedẹrun mi-in bẹẹ lawọn to jẹ arugbo paapaa ko ri anfaani gidi kan bayii jẹ ninu gbogbo owo ti kabiyesi ti gba lọwọ awọn to ta ilẹ ilu naa fun.
Iwọde lawọn eeyan yii ṣe lọ sileeṣẹ iwe iroyin lEkoo nibi ti wọn ti fidi ẹ mulẹ wi pe awọn ti fọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti, bẹẹ lawọn oloye ilu naa mọ si i daadaa, ṣugbọn ti won ko ri ohunkohun ṣe si i. Bẹẹ gẹgẹ ni wọn sọ pe awọn ti ba ọba alaye ọhun sepade lọpọ igba, ṣugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju awọn ja si.
Wọn ni pupọ ninu awọn ileeṣẹ nlanla bii Chevron, ileepo Shell atawọn mi-in ni wọn wa lori ilẹ Ajiran, ṣugbọn gbogbo anfaani to yẹ ki awọn ọmọ ilu maa jẹ, ọdọ ọba alaye yii lo n wọlẹ si.
Ẹsun tawọn eeyan yii fi kan ọba wọn ree, bẹẹ lo jọ pe Kabiyesi paapaa ko ṣetan lati ba awọn oniroyin sọ ohunkohun. Balogun ilu Ajiran, Alhaji Yẹkinni Bakare ni tiẹ sọ pe, lori iṣẹlẹ ọhun, ohun kan bayii ko ni i tẹnu oun jade.