Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ijọba ipinlẹ Ogun ti Gomina Ọmọọba Dapọ Abiọdun n dari, ti ni ko si ọmọ ipinlẹ Ogun kankan ninu awọn ti wọn sa lọ silẹ Olominira Benin nitori rogbodiyan awọn Fulani nilẹ Yewa.
Ọjọ Aje ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta, ọdun 202, ni ọrọ yii jade lati ẹnu alaga igbimọ to n ri si ija to n ṣẹlẹ laarin awọn agbẹ atawọn Fulani nipinlẹ Ogun, iyẹn Ọnarebu Kayọde Ọladele.
Ọfiisi awọn lọbalọba to wa ni Oke-Mosan, l’Abẹokuta, ni Ọladele ti sọ pe ahesọ lasan ni iroyin to n lọ lori ayelujara pẹlu awọn iwe iroyin kan, pe awọn ọmọ ipinlẹ Ogun, lati Yewa ti wa aabo lọ si Benin nitori awọn Fulani.
Ọladele sọ pe awọn ti wọn pada si Benin ko ju awọn ọmọ orilẹ-ede naa ti wọn waa n ṣiṣẹ agbẹ ni Yewa lọ.
O ni awọn eeyan naa ti wọn jẹ ẹya Họrọri ati Egun ko ṣẹṣẹ maa waa dako ni Yewa, awọn ọmọ oniluu yoo ya wọn ni ilẹ fawọn asiko kan, wọn yoo maa dako nibẹ, wọn yoo si maa lọ siluu wọn lẹẹẹkọkan. Awọn eeyan naa lo ni wọn pada si Benin nigba ti rogbodiyan ipaniyan Yewa bẹrẹ, o ni ki i ṣe awọn ọmọ Yewa rara.
Alaga naa sọ pe, ‘Lasiko abẹwo wa sawọn agbegbe ti wahala ti ṣẹlẹ ni Yewa, a de Abule Asá to jẹ ibi ti rogbodiyan ti lagbara gan-an, Adele Baalẹ to wa nibẹ sọ fun wa pe ẹru n ba awọn ara abule lati lọ soko nitori awọn Fulani, a gba wọn nimọran pe ki wọn ṣi ni suuru fungba diẹ naa ki wọn too maa lọ soko, to ba si di dandan fun wọn lati lọ, a ni ki wọn ri i pe wọn pọ lọ, ko ma jẹ ẹyọ ẹni kan ṣoṣo lo n da lọ soko. A ko sọ pe ki wọn pa oko wọn ti lai lọ mọ.
‘’Ẹ o si le ba ọmọ Yewa kankan ni Benin nitori ija awọn Fulani, awọn ajoji ni wọn pada sile wọn’’
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo ta ko Ọladele lori ohun to sọ yii, wọn ni bii ẹni to ri otitọ ọrọ nilẹ to si wu u ko maa parọ ni.