Kaakiri ipinlẹ ni awọn araalu ti n wa ile ẹru ti ijọba ko ounjẹ korona to yẹ ki wọn ti pin fun araalu, ṣugbọn ti wọn ko pin in bayii. Erongba wọn ni lati lọ sibe, ki wọn si pin ounjẹ naa laarin ara wa.
Ni bayii, ipinlẹ bii mẹta ni wọn ti ri awọn ounje naa tẹle, ipinlẹ Ondo naa ti kun wọn bayii pẹlu bi wọn ṣe ri ile ti wọn ko ounjẹ naa si to wa nitosi ile-ẹjọ giga to wa niluu Akurẹ. N ni awọn araalu ba ya bo ibẹ. Yẹbẹyẹbẹ ni wọn gbọn ile ounjẹ naa. Afigba ti wọn ko gbogbo ounjẹ to wa nibe tan ni ọjọ Abamẹta ki wọn too kuro nibẹ.
Ipinlẹ Eko ni wọn ti kọkọ bẹrẹ kinni naa, nigba ti wọn ri ile ẹru nla ti wọn ko awọn ounjẹ iranwọ korona yii si ni ibi kan ti wọn n pe ni Monkey Village, niluu Eko. Niṣe ni awọn eeyan ya bo ibẹ, ti wọn si ko gbogbo ohun jijẹ to wa nibẹ bii irẹsi, ororo, indomine ati bẹẹ beẹ lọ. Bẹẹ ni wọn ri ile ẹru yii mi-in ni Apapa, ti wọn si ko gbogbo ohun to wa nibẹ.
Afi bo ṣe di aarọ ọjọ Abamẹta ti ariwo tun gbalẹ pe wọn ti ri iru ile ounjẹ yii kan naa ni ilu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun. N lawọn araalu ba ya bo ibẹ, wọn si ko o tan patapata. Bẹẹ ni wọn ni awọn ara Ileṣa lọ si Irojo, nibi ti ijọba apapọ maa n ko ounjẹ pamọ si, ti wọn si ko gbogbo rẹ.
Ọrọ ko yọ ipinlẹ Kwara silẹ, niṣe lawọn eeyan ya bo ile ẹru yii, ti awọn naa si ko gbogbo ounjẹ to wa nibẹ.
Ibeere tawọn eeyan n beere ni pe ki lo de ti ijọba ko ounjẹ yii pamọ ti wọn ko si pin in fun araalu titi ti korona fi tan nilẹ pẹlu bawọn eeyan ṣe n pariwo ebi to lasiko korona.
Hmmmm ìkà àti onímò tá ra ẹni nìkan ni àwọn ìjọba wa, ni orile-ede Naijiria