Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn dokita to n ṣisẹ nileewosan ijọba kaakiri ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iyansẹlodi oni ikilọ latari ọpọlọpọ owo-osu tijọba jẹ wọn.
Dokita Taiwo Ọlagbe to gba ẹnu awọn ẹgbẹ rẹ sọrọ lasiko ti wọn lọọ fẹhonu han lọfiisi ọga agba patapata fun gbogbo awọn dokita ijọba laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni oṣu kẹrin ree ti awọn ti rowo osu gba gbẹyin.
Ọjọ Aiku, Sannde, lo ni iyansẹlodi onikilọ yii ti bẹrẹ, o si ṣee ṣe ki awọn tẹsiwaju ninu eyi ti ko ni i lọjọ kan pato to maa wa sopin tijọba ba fi kuna lati tẹti si ẹbẹ awọn titi di ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ.
Ọlagbe ni awọn n bẹ gbogbo ọmọ Naijiria ki wọn jọwọ, ba Gomina Akeredolu sọrọ lori ọrọ owo-osu awọn ti ki i san deede gẹgẹ bii tawọn oṣiṣẹ eleto ilera yooku.
Nigba to n ba awọn olufẹhonu han naa sọrọ, Dokita Adesina Adetan bẹ wọn ki wọn pada ṣenu iṣẹ wọn nitori araalu, o ni igbesẹ ti bẹrẹ lori gbogbo ohun ti wọn n beere fun lọdọ ijọba.
Gbogbo arọwa yii ko jọ bii ẹni wọ awọn dokita ọhun leti pẹlu bi wọn ṣe kọ lati pada ṣenu iṣẹ titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.