Awọn eeyan nla nla lorileede yii ti n ranṣẹ ibanikẹdun si mọlẹbi ọkan pataki ninu ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, to tun je minisita feto iroyin tẹlẹ nilẹ wa, lasiko iṣejọba Ọgagun Ibrahim Babangida, Ọmọọba Tony Momoh, to jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọrin.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ọkunrin naa mi imi ikẹyin ni oṣibitu alaadani kan niluu Abuja.
Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Kogi yii ni minisita fun eto iroyin lasiko isakoso Babangida. Awọn ọmọ Naijiria ko si ni i gbagbe ọkunrin naa bọrọ pẹlu ọrọ kan to maa n sọ lasiko ti wọn n ṣe ipolongo ibo fun Buhari pe ‘Ẹ sọ wa loko pa ti a ko ba ṣe ijọba daadaa ta a ba debẹ’’
Ọjọ kẹtandinlọgbọ, oṣu kẹrin, ọdun 1939, ni wọn bi ọkunrin ọmọ bibi ilu Auchi, nipinlẹ Edo, to wa lati idile ọmọba yii. Oniroyin to dangajia ni, o tun jẹ agbẹjọro, bẹẹ lo si jẹ oloṣelu.
O ti ṣiṣẹ lawọn ileeṣẹ iweeroyin to lorukọ kaakiri ilẹ wa atawọn ileeṣẹ nla nla mi-in.
Latigba ti wọn ti kede iku ọkunrin naa ni awọn eeyan nla nla lawujọ, awọn oloṣelu atawọn afẹnifẹre ti n ranṣẹ ibanikẹdun si mọlẹbi ọkunrin oloṣelu naa.