Stephen Ajagbe, Ilorin
Bii igba ti wọn ba wa loju ogun ni ọrọ ri lana-an, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni olu ileeṣẹ ajọ aṣọbode niluu Ilọrin, nigba tawọn janduku kan to waa kọ lu ọfiisi naa gbena woju ara wọn pẹlu awọn ọmọ ileeṣẹ ologun.
AKEDE AGBAYE gbọ pe awọn eeyan fara gba ọta nibi iṣẹlẹ naa, bẹẹ lawọn oṣiṣẹ aṣọbode meji farapa, wọn ti wa nibi ti wọn ti n gba itọju.
Alukoro ileeṣẹ naa, Zakari Chado, ṣalaye pe nnkan bii aago mẹrin aabọ irọlẹ lawọn janduku ọhun balẹ si ọfiisi awọn, pẹlu awọn ọkada ati kẹkẹ Maruwa ti wọn gbe wa lati fi ji ẹru ko.
O ni oriṣiiriṣii ohun ija oloro bii ibọn, aake, ada ati oogun ni wọn ko wa lati koju awọn, bi wọn ṣe de ni wọn dana si gbogbo abawọle ileeṣẹ naa. Bẹẹ ọga agba ajọ naa, Ahmed Hussaini Bello, ṣi wa lọfiisi lasiko tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. Oun lo kegbajare si ileeṣẹ ologun lati waa ran wọn lọwọ tawọn yẹn fi ko ṣọja wa.
Chado ni gbogbo akitiyan awọn lati pẹtu sawọn janduku ọhun ninu lo ja si pabo, ṣe ni wọn bẹrẹ si i yinbọn, ti wọn si n kọlu awọn oṣiṣẹ ajọ naa ti wọn ri, eyi lo mu ki awọn ṣọja to wa nibẹ dana ibọn ya wọn pada.
A gbọ pe bii ogoji iṣẹju lawọn igun mejeeji fi rọjo ibọn lu ara wọn, nigbẹyin, ere lawọn janduku naa pada sa kuro nibẹ nigba ti wọn ri i pe nnkan ju nnkan lọ.
Ọkada mẹrinlelogun ati kẹkẹ Maruwa kan lo ni awọn ri gba lọwọ awọn janduku to fẹsẹ fẹ ẹ naa.
Chado ni ileeṣẹ naa yoo sa gbogbo ipa lati daabo bo dukia ijọba lọna yoowu to ba ba ilana ofin mu. Fun idi eyi, ajọ naa gba awọn obi ati adari adugbo nimọran lati kilọ fun awọn ọmọ wọn.