Awọn eeyan Ido-Ọṣun yari, wọn l’Adeleke ko gbọdọ gbe papakọ ofurufu kuro niluu naa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Nitori bi Gomina Ademọla Adeleke ṣe fẹẹ gbe papakọ ofurufu ti ibujoko rẹ wa niluu Ido-Ọṣun, nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ, nipinlẹ Ọṣun, lọ siluu Ẹdẹ, awọn ọmọ bibi ilu naa ti sọ pe igbesẹ to le da wahala silẹ laarin ilu mejeeji ni.

Wọn ni ki lo de to jẹ pe ohun kan ṣoṣo ti awọn n wo loju lati ọdun 1936, to ti wa nibẹ lo tun wu gomina lati gbe kuro lọ siluu abinibi rẹ l’Ẹdẹ.

Laipẹ nijọba Ọṣun kede pe wọn yoo ṣe ifilọlẹ ibudo miiran fun papakọ ofurufu ipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun yii. Lara awọn alakalẹ eto fun ayẹyẹ ọdun keji iṣejọba Gomina Adeleke ni wọn fi eto ọhun si.

Wọn ni ibudo ti papakọ ofurufu naa wa bayii niluu Ido-Ọṣun, ti kere ju latari bi awọn kan ṣe ti kọ ile sibẹ, niwọn igba to si jẹ pe ilu Ẹdẹ nikan lawọn ti ri ilẹ to tobi, idi niyẹn tawọn fi pinnu lati gbe e lọ sibẹ.

Ṣugbọn nibi ifẹhonuhan wọọrọwọ tawọn eeyan ilu Ido-Ọṣun ṣe, aṣojuu wọn, ẹni to ti figba kan jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Abiọdun Awolọla, ti sọ pe irọ to jinna sootọ ni awawi tijọba wi.

O ni ti wọn ba n sọ pe awọn kan kọle sori ilẹ papakọ ofurufu naa, ileewe Adeleke University High School, gan-an lo tobi ju nibẹ, o ni ki lo de ti wọn ko le wo o lulẹ.

Awolọla sọ siwaju pe ko si eyikeyii ninu awọn gomina ti wọn ti jẹ l’Ọṣun ti wọn gbe igbesẹ lati gbe ibudo naa kuro ni Ido-Ọṣun, lọ siluu abinibi wọn.

O ni latigba ti ọba awọn, Oludoo ti Ido-Ọṣun, Ọba Aderẹmi Adedapọ, ti waja ni awọn Ẹdẹ ti n wa gbogbo ọna lati lo agbara ijọba le awọn lori, ti wọn si n fin awọn niran.

Awolọla ni, “Bi wọn ṣe n fi baalẹ jẹ lori ilẹ to jẹ tiwa, bẹẹ ni wọn n daamu awọn agbẹ ilu naa ti wọn wa ninu oko nipa tita ilẹ wọn, paripari rẹ ni bi wọn ṣe fẹẹ fi ẹni ti ko tọ jẹ ọba le wa lori lọsẹ diẹ sẹyin, eleyii ti awa ilu ko gba fun wọn.

“Gbogbo iwa ti wọn n hu lati da wahala silẹ la ko gba laaye, bẹẹ si ni a ko ni i gba wọn laaye lati gbe papakọ ofurufu to ti wa niluu wa ki wọn too bi ọpọlọpọ wọn yii naa kuro.

“Ki lo de tijọba fẹẹ sọ gbogbo nnkan di ti ilu Ẹdẹ, nitori pe gomina wa latibẹ. Ọpọ iṣẹ idagbasoke to yẹ ko wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun ni wọn n ko siluu Ẹdẹ.

“Owo to to biliọnu marun-un Naira lawọn ijọba to ti kọja lọ ti na lori ibudo yii, iwa ti ko bojumu rara ni kijọba Adeleke waa tun lọọ bẹrẹ ibudo tuntun nitori pe wọn ko fẹ ko wa niluu Ido-Ọṣun.

“A n ke si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lati ba wa da si ọrọ naa, ki wọn jẹ kijọba Ọṣun mọ pe owo idagbasoke gbogbo araalu ni wọn n fi ranṣẹ si Ọṣun, ki i ṣe fun awọn eeyan ilu Ẹdẹ nikan.

“Ki awọn minisita fun ọrọ irinna ofurufu ati ti iṣẹ-ode; Festus Keyamọ ati David Umahi, ma ṣe wa sibi ifilọlẹ papakọ ofurufu tuntun tijọba Ọṣun fẹẹ ṣe loṣu to n bọ naa, nitori wiwa wọn yoo fi han pe awọn naa fara mọ iwa anikanjọpọn ti awọn ilu Ẹdẹ n hu nipinlẹ Ọṣun.

“Olufẹ alaafia ni wa ni Ido-Ọṣun, tori naa, ki ijọba ba wa fi papakọ ofurufu yii silẹ. A ko fẹ nnkan to tun le hu iru wahala Ifọn/Ilobu jade lagbegbe tiwa.” Bẹẹ ni Awolọla wi

Leave a Reply