Awọn eeyan Ikẹrẹ-Ekiti fẹẹ kọ teṣan ọlọpaa tawọn janduku dana sun

 

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn eeyan Ikẹrẹ-Ekiti ti pinnu lati kọ awọn teṣan ọlọpaa tawọn janduku dana sun lasiko rogbodiyan to waye laipẹ yii pada.

Lẹyin ipade nla kan tawọn eeyan naa ṣe pẹlu awọn adari agbegbe, awọn ọdọ atawọn mi-in ni wọn sọ pe o di dandan lati gbe igbesẹ ọhun nitori eto aabo.

Tẹ o ba gbagbe, lasiko rogbodiyan to ṣẹlẹ lẹyin iwọde EndSARS lawọn janduku lọọ jo ọlu-ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Ikẹrẹ-Ekiti ati teṣan meji mi-in, eyi to jẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa ko awọn eeyan wọn kuro nibẹ.

Lẹyin ipade naa ni Ọba Adejimi Adu fọwọ si akọsilẹ kan lorukọ awọn eeyan ilu naa, ninu eyi ti wọn ti ro ọga ọlọpaa kan to ti fẹyinti lagbara lati ṣeto bi agọ ọlọpaa kan ti wọn n kọ lọwọ yoo ṣe tete pari.

Awọn ara ilu naa waa bẹnu atẹ lu iwa awọn to da rogbodiyan naa silẹ, bẹẹ ni wọn ṣeleri pe awọn yoo ran awọn ọlọpaa lọwọ lati mu awọn to lọwọ si idaluru naa, wọn si bẹ wọn lati da awọn agbofinro pada siluu naa.

 

 

Leave a Reply