Aderounmu Kazeem
Ko si ọmọ ilu Ipetu-Ijẹṣa nipinlẹ Ọṣun to gbọ nípa wahala to sẹlẹ láàrin Ọwá Obòkun Ilẹ Ìjẹ̀ṣà, Ọba Adekunle Aromọlaran ati Ọba wọn, Ajalaye ti Ipetu Ìjèṣà, Ọba Adeleke Agunbiade, ti inu ko maa bi gidigidi lori bi Ọwa Obokun ṣe fun baba naa ni igbati meji nita gbangba.
Ninu atẹjade ti olùrànlọwọ nipa iroyin fun Ajalaye ilu Ipetu Ijeṣa, Afọlábí Akinọla, fi sita lo ti bu ẹnu atẹ lu iwa idojutiní ti Obòkun hu si Ajalaye pẹlu bo ṣe fọ ọ leti lẹẹmeji leralera.
O ni, “Eyi ni lati fi to gbogbo eeyan leti nipa iwa ifiyajẹni ati idojutini nita gbangba ti Ọwa Obokun ti ilu Ileṣa ṣe fun Ọba wa, Adeleke Agunbiade, nibi ayẹyẹ kan laipẹ yii lori ẹsun wi pe kabiyesi ko ki i bo ti yẹ.
“Ẹẹmeji ọtọtọ ni Ọwa gba ọba wa leti, bẹẹ abuku nla ni eleyii jẹ fun gbogbo ilẹ Ipetu Ijẹṣa, bẹẹ lo lodi si ofin awọn alalẹ. Ohun ibanujẹ lo jẹ fun mi lori bi awọn oniroyin ṣe n pe mi lati fidi ọrọ ọhun mulẹ, eyi to mu mi pe Olori Bọla Agunbiade, ti wọn si ti fi da mi loju bayii pe Ajalaye ti tori iwa buruku yii pe Ọwa Obokun lẹjọ.
“Pẹlu iṣẹlẹ yii, mo fẹẹ fi asiko yii ke si ijọba ipinlẹ Ọṣun lati paṣẹ fun Ọwa ko fi ori apere Ọba to wa silẹ ko lọọ rọ ọ kun nile na, nitori iwa idojutini gbaa lo hu si ọba ẹgbẹ ẹ, bẹẹ nirufẹ iwa bẹe ko yẹ ọba alade. Abuku nla ni eleyii jẹ fun wa nilẹ Ipetu Ijẹṣa, bẹẹ la o ni i fọwọ kekere mu un rara.”