Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ara-ọtọ patapata ni eto idibo gbogbogboo ti wọn di lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun ta a wa yii, jẹ nipinlẹ Ondo pẹlu bawọn eeyan ṣe kọ lati jade dibo gẹgẹ bii iṣe wọn nigbakuugba ti eto idibo ba ti n waye.
Bo tilẹ jẹ pe aago mẹjọ aarọ ko ti i lu rara tawọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ti wa lawọn ojuko ibi ti eto yii ti fẹẹ waye ni awọn agbegbe ta a ṣabẹwo si niluu Akurẹ, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, Ọba-Ile, Ilu Aabo ati Ọgbẹsẹ, eyi to wa nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, Uṣo, Emure-Ile, Ọwọ, Ìjẹ̀bú-Ọwọ, n’ijọba ibilẹ Ọsẹ, pẹlu ilu Ondo, nibi ta a ti ri ijọba ibilẹ meji ọtọọtọ, iyẹn Iwọ-Oorun ati Ila-Oorun Ondo, iwọnba awọn eeyan perete la ri ti to to sori ila, ti wọn si n dibo.
Nnkan bii aago mọkanla ku bii iṣẹju mẹwaa aarọ ni Gomina Rotimi Akeredolu de si ibudo idibo rẹ ni Wọọdu Karun-un, Yniiti kẹfa, Ìjẹ̀bú-Ọ̀wọ̀, nijọba ibilẹ Ọwọ. Koda awọn eeyan kan ti n ṣiyèméjì pe o ṣee ko ma le yọju sibẹ lọjọ naa nitori ki i pẹ to bẹẹ ko too waa ṣe ojuṣe rẹ ninu awọn eto idibo to ti waye sẹyin lati bii ọdun mẹfa to ti wa lori aleefa.
Lẹyin ti Aketi tun de nkọ, o to bii ogun isẹju ti wọn fi wa lori oun nikan pẹlu bi ẹrọ BVAS, eyi ti wọn kọkọ fi n sayẹwo awọn oludibo to kunju oṣuwọn ṣaaju idibo wọn ṣe kọ lati gba aworan rẹ wọle loju-ẹsẹ.
Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ lẹyin to dibo tan, Arakunrin fi ẹdun ọkan rẹ han lori iwọnba awọn oludibo perete ti wọn jade lati ṣe ojuṣe wọn, o ni oun nigbagbọ pe awọn eeyan ṣi tun le jade si i niwọn igba ti eto naa ṣi n tẹsiwaju, ti ọjọ ko si ti i fi bẹẹ lọ pupọ, iyẹn lasiko to n sọrọ naa.
Awọn ero jade daadaa ni Yuniiti kẹrindinlogun, Wọọdu kọkanla, ni Uṣo/Emure, eyi ti ko fi bẹẹ jinna si Ọwọ, nibi ti ọkan ninu awọn adari ipolongo Tinubu lẹkun Iwọ-Oorun, Ọgbẹni Alex Ajipẹ ti dibo.
Loootọ, ki i ṣe pe a ribi ti wọn ti n pin owo lojukoju ṣùgbọ́n ohun ta a ṣakiyesi ni pe awọn eeyan kan wa nitosi ibi ti wọn ti n tẹka, ti wọn ṣọ awọn oludibo lọwọ lẹsẹ bi wọn ṣe n dibo.
Ẹnikan to ba wa sọrọ laṣiiri ni awọn eeyan ko kọkọ fi bẹẹ jade latari bi awọn oloṣelu agbegbe ọhun ko ṣe ri owo pin fun wọn, o ni lẹyin-o-rẹyin ni wọn ṣẹṣẹ tu jade waa dibo nigba ti wọn gbọ pe o ṣee ki awọn ri owo gba.
Ọkunrin to ba wa sọrọ ọhun ni, ẹdun ọkan patapata lo jẹ lori bi awọn oludibo ko ṣe fẹẹ maa jade lati ṣe ojuṣe wọn mọ nibi ti wọn ko ba ti fun wọn lowo.
Ọpọlọpọ arọwa ni Ọba Kofoworọla Ọladẹhinde Ọjọmọ, Ọjọmọluda Olijẹbu ti Ijẹbu-Ọwọ, ni awọn ọba alaye pa fawọn eeyan lati jade ki wọn ṣe ojuṣe wọn nitori ti wọn ba kọ lati ṣe bẹẹ, o ṣee ṣe ki awọn ti ko loye tabi ni imọlara nipa iya to n jẹ awọn araalu ṣi tun tẹsiwaju lati maa wa nipo.
Lori bawọn araalu ko ṣe ṣe bẹẹ jade to lati dibo, Ọba Ọjọmọ ni ko sohun to buru ninu ofin owo Naira ti banki apapọ ṣẹṣẹ gbe jade fawọn eeyan orílẹ̀-ede yii lati ṣamulo, ṣugbọn gbedeke ati asiko ti wọn gbe kinni ọhun kalẹ ni ko bojumu.
O ni ọpọ awọn araalu lọkan wọn fẹ lati lọọ dibo, ṣugbọn to ṣee ṣe ki wọn ma ni owo lọwọ, eyi ti wọn yoo fi wọ ọkọ tabi gun ọkada lọ, bẹẹ ọlọkada ko si ni i gbero ọfẹ latari ọwọngogo epo bẹntiroolu.