Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lẹyin bii ọjọ mẹrin ti wọn ti n wa ọga agba kan nileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ ile-iwe girama nipinlẹ Ondo (TESCOM), Ọgbẹni Ọlọfingboyegun Gbenga, ni wọn ri oku rẹ ninu kilaasi ileewe alakọọbẹrẹ kan niluu Akurẹ, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an, ọdun ta a wa yii lawọn ẹbi ọkunrin ti wọn pa ọhun kede pe awọn n wa a pẹlu bi wọn ṣe lo deede dawati lẹyin to kuro lọfiisi rẹ lẹyin iṣẹ ọjọ naa.
Gbogbo ero awọn ẹbi rẹ ni pe o ṣee ko jẹ awọn ajinigbe ni wọn ji i gbe, asiko tawọn to ji i gbe yoo si pe wọn lati beere owo itusilẹ ni wọn n reti nigba ti wọn gbọ iroyin mi-in lojiji pe wọn ti ri oku rẹ ninu ọgba ileewe alakọọbẹrẹ Teresa Mimọ, eyi to wa nitosi ileewe Yuniiti ijọba, ni opopona Oyemẹkun, l’Akurẹ.
Awọn to ri oku rẹ ki wọn too gbe e lọ si mọṣuari sọ pe kootu ati tai to wọ lọ sibi iṣẹ lọjọ ti wọn kọkọ ji i gbe lo ṣi wa lọrun rẹ, yatọ si ori rẹ ti wọn ti ge lọ, wọn ni niṣe ni wọn tun la aya rẹ lati yọ awọn ẹya ara mi-in ninu ara rẹ.
Nigba ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o ni oun ko ti i le sọ ni pato iru ẹni ti oloogbe naa jẹ.
Nnkan mi-in ta a tun gbọ lati ẹnu ẹnikan to sun mọ oloogbe ọhun pẹkipẹki, ṣugbọn ta a forukọ bo laṣiiri ni pe ko ti i ju bii oṣu meji pere to ṣẹṣẹ gba igbega lẹnu isẹ ọba to n ṣe, bo tilẹ jẹ pe ko ti i tẹwọ gba kọbọ gẹgẹ bii owo ipo tuntun ti wọn gbe e si naa titi to fi pade iku gbigbona yii.
O ni ọdun kẹtalelogun ree to ti wa lẹnu iṣẹ ijọba, nitori ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 1999 ti wọn gba a ṣiṣẹ.