Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Gbogbo awọn iyalọja, kẹkẹ Maruwa, ọlọkada atawọn oniṣẹ ọwọ, ni wọn n ba eto ọrọ aje wọn lọ niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, lai naani iwọde “June 12” ti awọn eniyan kan n pariwo.
Aago mẹwaa owurọ yii ni Aakọroyin ALAROYE lọ kaakiri awọn agbegbe to ṣe koko nilu naa lati wo bi nnkan ṣe n lọ lori “June 12”, ṣugbọn ko tiẹ si iyatọ laarin ọjọ lasan ati ayajọ awa-ara-wa yii. Ṣe ni onikaluku gbaju mọ isẹ rẹ lawọn adugbo bii
Ọja Ọba, Ọja Ipata, Ọja Ọlọjẹ, (Post Office), Salẹnji (Challenge), Mọraba, Sango, Taiwo ati bẹẹ bẹẹ lọ, gbogbo agbegbe yii ni a rin de, ti a si ri pe gbogbo nnkan lọ deede.
Bakan naa lọrọ ri niluu Sao, Malete, Jẹbba, Ọffa, Omu-Aran ati awọn ilu miiran ni Kwara, gbogbo nnkan ti n lọ lẹrọ wọọrọ. Ko si ipejọ kankan to fara pẹ iwọde rara.