Jide Alabi
Pẹlu ibinu lawọn araalu fi n ke si ileefowopamọ FCMB lati tete le ọga banki ọhun danu lori ẹsun ti wọn fi kan an pe oun lo bayawo oniyawo sun tọkọ iyẹn fi ronu ku.
Ori ikanni abẹyẹfo ni wọn kọkọ gbe iroyin ọhun si lọjọ ọdun tuntun, bi awọn eniyan si ti ri i, ti wọn ka gbogbo bo ṣe ṣẹlẹ ni wọn ti n gbe ọga banki FCMB, Ọgbẹni Adam Nuru, ṣepe nla, ti wọn si n sọ pe niṣe lo fi ọwọ ọla gba Oloogbe Tunde Thomas, loju.
Tunde Thomas yii ni wọn sọ pe o ronu ku nigba ti iyawo ẹ, Moyọ Thomas, sọ fun un pe ko ma wulẹ da ara ẹ laamu mọ o, ilu Amẹrika ti oun wa, oun ko ṣetan ile, ati pe ọmọ meji to ro pe oun loun ni wọn yẹn, ọga oun ni banki FCMB loun bi wọn fun, ko ni ọmọ kankan lọdọ toun.
Nibi ti wọn sọ pe wahala ti de ba ọkunrin yii niyẹn, ti aisan rọpa-rọsẹ si ṣe bẹẹ kọ lu u, lẹyin ẹ naa lo tun pada ku lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kejila, ọdun to pari yii.
Ohun ti awọn araalu n sọ bayii ni pe banki FCMB gbọdọ le ọkunrin naa lẹnu iṣẹ, bẹẹ lo yẹ ko tun jiya labẹ ofin, nitori iwa to hu yii, ki i ṣe ohun to bojumu rara fun ọmọluabi, bẹẹ lo le ṣakoba fun orukọ rere ti ileefowopamọ ọhun ti ni.
Ni bayii, lori ikanni ayelujara nikan, awọn eeyan ti wọn fẹẹ to ẹgbẹwa (1,927) ni wọn ti fọwọ si i bayii pe wọn gbọdọ le ọkunrin yii ni banki FCMB ni. Bakan naa ni wọn tun sọ pe banki agba ilẹ Naijiria, iyẹn CBN, paapaa gbọdọ fofin de e pe ko gbọdọ ṣiṣẹ mọ, nitori to n ba ọmọọṣẹ ẹ sun, paapaa bi iyẹn ti ṣe jẹ iyawo ile, to si tun bimọ meji fun un ninu iwa agbere wọn.
Ni bayii, ileefowopamọ naa ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan ọgba agba ẹ yii.
Ṣa o, ninu ọrọ ti agbẹnusọ fun ileefowopamọ naa, Ọgbẹni Diran Ọlọjọ, sọ, lo ti sọ pe awọn alaṣẹ ileefowopamọ ọhun ni yoo sọ boya Adam Nuru yoo si maa tẹ siwaju pelu iṣẹ ẹ bi iwadii ṣe n lọ lọwọ, tabi yoo fiṣẹ silẹ na.
O ni gbogbo bo ṣe n lọ lori ikanni oriṣiriiṣii lori ẹrọ ayelujara ni banki ọhun ti ri, bẹẹ ni igbesẹ ti n lọ lọwọ laarin awọn ọga agba lati tọpinpin bi ọrọ ọhun ṣe jẹ gan-an.