Gbenga Amos, Abẹokuta
Ọwọ palaba awọn afarasi ajinigbe meji kan, Usman Umaru ati Ibrahim Muhammed, segi. Nibi ti wọn ti n pete pero bi wọn ṣe maa ji Fulani ẹlẹgbẹ wọn, Suleiman Mohammed, gbe, lawọn ọlọpaa ka wọn mọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’AKEDE AGBAYE lori ikanni Wasaapu l’Ọjọbọ, Tọsidee, pe ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, to kọja, lọwọ awọn agbofinro tẹ awọn afurasi mejeeji ọhun niluu Imẹkọ.
Suleiman lo lọọ ta awọn ọlọpaa teṣan Imẹkọ lolobo pe ẹnikan toun o mọ n pe sori foonu oun, onitọhun si ti fi nọmba ẹ pamọ, o lo dunkooko mọ oun pe awọn maa ji oun gbe laipẹ, oun si le fiku ṣe’fa jẹ toun o ba tete lọọ san miliọnu marun-un Naira fawọn.
Nigba toun bẹ ẹni naa pe oun o lowo to to bẹẹ lọwọ, ki wọn ṣaanu oun, o lẹni naa fesi pe koun lọọ ta awọn maaluu toun n sin, koun fi sanwo tawọn beere naa, ko si gbọdọ kọja gbedeke asiko tawọn da.
Bi wọn ṣe gbọrọ yii, loju-ẹsẹ ni DPO teṣan Imẹkọ, CSP Ubine Eugine, ti ṣeto pe kawọn ọtẹlẹmuyẹ lọọ ṣewadii nipa ọrọ naa, wọn lo awọn ẹrọ igbalode to le taṣiiri nọmba foonu ti wọn fi pamọ, ati ibi tẹni naa ti n pe, laṣiiri ba tu pe inu igbo kan ni laarin ilu Iwoye ati Idọfa lawọn afurasi mejeeji naa ti n sọrọ, ni wọn ba ko wọn.
Nigba ti wọn de tọlọpaa, wọn jẹwọ pe ẹni mimọ ni Suleiman jẹ fawọn, aburo Suleiman ni ọkan ninu wọn fẹ, ana Suleiman yii lo fun ekeji ẹ lọwọ bi wọn ṣe maa rin in lati ji i gbe, wọn lawọn fẹẹ dọgbọn gba owo nla lọwọ ẹ ni, tori ki i fawọn lowo tawọn ba tọrọ owo lọwọ ẹ, wọn ni ahun ẹda kan ni.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti gbọ sọrọ yii, CP Lanre si ti paṣẹ kawọn afurasi ọdaran mejeeji ṣi maa gbatẹgun lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ, ni ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ijinigbe. Ibẹ lo ni wọn maa gba dele-ẹjọ.