Awọn eleyii fẹẹ ji ọga ileeṣẹ wọn gbe tori owo

Gbenga Amos, Ogun

Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ba awọn afurasi ajinigbe mẹta kan, Peter Nse, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Micheal Umanah, ẹni ọgbọn ọdun ati Chukwuma Nwobodo, ẹni ọdun mejidinlaaadọta. Ẹṣẹ ti wọn da ni pe wọn gbimọ-pọ lati ji Ọgbẹni Ọlayinka Ifẹnuga, ọga agba ileeṣẹ wọn gbe.

Ọga ileeṣẹ naa lo sare janna-janna lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Igbeba, lagbegbe Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, o lọọ fi atẹjiṣẹ ọran kan to wọ ori foonu rẹ han wọn.
Ninu atẹjiṣẹ naa ni wọn ti sọ fun un pe ko tete lọọ fi miliọnu marun-un Naira ṣọwọ ni kiakia sinu nọmba akaunti banki kan tawọn kọ sabẹ atẹjiṣẹ naa, aijẹ bẹẹ, o maa ba ara ẹ lakata awọn ajinigbe laipẹ, tori awọn ti n ṣọ ọ, awọn si ti wa layiika ẹ. Wọn tun dunkooko mọ ọn pe o le fiku ṣefa-jẹ bi ko ba tete ṣe nnkan tawọn ni ko ṣe.
Ko si nọmba pato nipa ẹni to fi atẹjiṣẹ naa ranṣẹ, orukọ to gbe wa ni “Killer Vagabond of Africa,” eyi to tumọ si “Apaayan ilẹ Afrika ti o ṣe e mu.”

Bọrọ yii ṣe to DPO teṣan naa, CSP Musiliu Doga, leti, lo ti paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii ijinlẹ lori ẹsun ọhun.

Lẹyin tawọn ọtẹlẹmuyẹ ti fimu-finlẹ, ti wọn si tun lo awọn ẹrọ igbalode to n yẹ tifun-tẹdọ foonu wo, olobo ta wọn pe ipinlẹ Anambra lawọn to pete ibi naa wa, wọn tẹkọ leti lọ sibẹ, ibẹ si lọwọ wọn ti ba Peter ati Chukwuma.

Nigba tiwadii tẹsiwaju ni awọn tọwọ tẹ naa jẹwọ pe ẹni kẹta tawọn jọ n gbomi ọbẹ ijinigbe yii kana ni Micheal, wọn l’Agọ-Iwoye lo n gbe, ọwọ si tẹ oun naa.

Awọn agbofinro pe ọga ileeṣẹ to waa fẹjọ sun lati foju-rinju pẹlu awọn afurasi ti wọn fẹẹ ji i gbe, ẹnu ya a gidi. O lawọn mẹtẹẹta loun mọ, tori wọn ti ṣiṣẹ nileeṣẹ oun ri, oun loun si gba wọn siṣẹ, bo tilẹ jẹ pe niṣe loun le wọn danu nigba ti wọn bẹrẹ si i huwa palapala lẹnu iṣẹ.

Awọn afurasi naa jẹwọ pe loootọ ni awọn ti ṣiṣẹ nileeṣẹ ọga awọn yii ri, wọn nidii tawọn fi pinnu lati ji i gbe gan-an ni pe bo ṣe le awọn danu lẹnu iṣẹ ko tẹ awọn lọrun, awọn si fẹẹ fiya jẹ ẹ tori ẹ, eyi lo mu kawọn da ọgbọnkọgbọn ti awọn da yẹn.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe kawọn ọtẹlẹmuyẹ ni ẹka ti wọn ti n gbogun ti iwa ijinigbe lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Eleweeran, l’Abẹokuta, tubọ ṣẹwadii to lọọrin nipa iṣẹlẹ yii. Ibẹ lawọn afurasi ọdaran mẹtẹẹta naa wa bayii, ibẹ si ni wọn maa gba sọda sile-ẹjọ tiwadii ba ti pari gẹgẹ bi Alukoro awọn ọlọpaa Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe sọ.

Leave a Reply