Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Nitori ti wọn lu ọga wọn ni jibiti miliọnu mẹrinlelọgọsan-an Naira, oluṣiro owo ileeṣẹ burẹdi Fortunate, niluu Ilọrin, Abdulraman Abdulateef Oriyọmi, ati oṣiṣẹ wọn mi-in, Abiọdun Oyedele, ni adajọ ti ni ki wọn maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn Oke Kura, titi ti igbẹjọ yoo fi waye lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn.
Oludasilẹ ileeṣẹ burẹdi naa, Alaaji Adejumọ Akeem, lo fi panpẹ ofin gbe wọn, to si gbe wọn lọ silẹ-ẹjọ. O sọ fun kootu pe Oriyọmi jẹ oluranlọwọ pataki si oun, ṣugbọn o gbimọ-pọ pẹlu Oyedele, toun naa jẹ oṣiṣẹ nileeṣẹ naa ti wọn fi lu oun ni jibiti miliọnu mẹrinlelọgọsan-an Naira (184million), ti wọn ko si le ṣe iṣiro ọna ti owo naa gba poora.
O tẹsiwaju pe ọmọkunrin naa to wa lati ijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara, jẹ akọwe (secretary) ileeṣẹ naa laarin ọdun 2018, o di oluṣiro owo (accountant) lọdun 2022, o si di ayẹwe- owo wo (auditor) ni oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.
Ninu ọrọ rẹ, Agbefọba, Gbenga Ayẹni, rọ ile-ẹjọ lati sọ awọn afurasi naa satimọle titi ti iwadii yoo fi pari.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Gbadeyan Kamson, paṣẹ ki wọn sọ awọn afurasi mejeeji sẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi waye lọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.