Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajọ A. Demi-Ajayi, tile-ẹjọ giga kan to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ni wọn foju awọn gende mẹta kan ti wọn ti jingiri ninu jiji waya ina ijọba ka ba. Awọn mẹta ti wọn foju wọn bale-ẹjọ laipẹ yii ni Ọgbẹni Chibueze Emmanuel, Ojuọlape Ọlaitan ati Michael Genesis. Waya ina ileeṣẹ kan to n pese ina mọnamọna fawọn araalu ti wọn n pe ni ‘Ibadan Electricity Distribution Company’ (IEDC), to wa nijọba ibilẹ Ijẹbu North East, ni wọn lọọ ji ka lọdun 2022, latigba naa ni wọn ti wa lahaamọ ọgba ẹwọn nipinlẹ Ogun, ko too di pe wọn ṣedajọ wọn lọsẹ to kọja yii.
ALAROYE gbọ pe ọga ajọ sifu difẹnsi ‘Nigeria Security And Civil Defence Corp’ (NSCDC), ẹka tipinlẹ Ogun, Ọgbẹni David Ọjẹlabi, lo kọkọ ṣafihan awọn afurasi ọdaran ọhun fawọn oniroyin lọdun 2022, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, pe agbegbe Imọmọ, nijọba ibilẹ Ijẹbu North-East, lọwọ ti tẹ Ojuọlape Ọlaitan, ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin, lẹyin tawọn araalu fọrọ rẹ to awọn leti. Ẹnu iṣẹ ti ko bofin mu yii ni wọn ti ba a, ti wọn si fọwọ ofin mu un ju sahaamọ.
Alukoro ajọ ọhun, Ogbeni Dyke Ogbonnaya, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun yii, sọ pe ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun 2022, ni ọwọ tẹ Chibueze Emmanuel ati Michael Genesis, lasiko ti wọn n ji waya ina ijọba agbegbe naa ka, wọn ba ọpọ waya ina lọwọ wọn, wọn si fọwọ ofin mu wọn ju sahaamọ.
Lasiko ti wọn foju awọn afunrasi ọdaran ọhun bale-ẹjọ, wọn lawọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn pẹlu alaye.
Lẹyin ti adajọ ile-ẹjọ ọhun yẹ awọn ẹri to wa niwaju rẹ wo daadaa, ẹwọn ọdun mẹfa pẹlu iṣẹ asekara lọgba ẹwọn ni adajọ ju awọn mẹtẹẹta si, o ni idajọ ọhun maa kọ awọn araalu yooku lẹkọọ.