Awọn eleyii ti ha o, aṣẹwo ti wọn fẹẹ ba sun ni wọn ja lole

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Adeniran Ogunsanya, ni Bọde Thomas, Suurulere, nipinlẹ Eko, ni awọn afurasi ọdaran meji kan tawọn ọlọpaa lawọn ko darukọ wọn wa bayii.

ALAROYE gbọ pe Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni awọn afurasi ọdaran naa ni ara awọn kun, ni wọn ba lọ si agbegbe Adeniran Ogunsanya, wọn lọọ gbe alaṣẹwo meji ti wọn maa ba sun. Wọn jọ dunaa dura owo, lẹyin ti ọrọ wọ tan ni wọn ba sọ pe kawọn aṣẹwo naa wọnu mọto Toyota Camry alawọ eeru kan ti wọn gbe wa. Lasiko ti wọn n lọ loju ọna ni awọn afurasi ọdaran meji naa ti yọ ibọn sawọn aṣẹwo yii, ti wọn si gba foonu igbalode iPhone tiye rẹ jẹ miliọnu kan aabọ Naira, ati foonu Redmi-Note 12, towo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ogoje Naira lọwọ wọn. Lẹyin naa ni wọn tun kan an nipa fawọn aṣẹwo naa pe ki wọn fowo to wa ninu akanti wọn ṣọwọ sawọn lori foonu. Wọn gba ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn Naira lọwọ ẹni kan, nigba ti wọn tun gba ẹgbẹrun mẹjọ Naira lọwọ aṣẹwo keji.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ yii, sọ pe ọkan lara awọn aṣẹwo tawọn afurasi ọdaran naa ja lole lo tọka awọn afurasi ọdaran naa fawọn ọlọpaa, tawọn agbofinro si fọwọ ofin mu un loju-ẹsẹ nibi to wa.

Lara awọn ohun ti wọn ba lọwọ awọn afurasi ọdaran naa ni foonu Redmi-Note 12 ti wọn fipa gba lọwọ aṣẹwo kan atawọn ẹru mi-in ti wọn ko le ṣalaye bo ṣe jẹ fawọn ọlọpaa.

Alukoro ni awọn maa too foju wọn bale-ẹjọ laipẹ yii, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn.

 

Leave a Reply