Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ninu eto idibo gomina to waye lọjọ kẹwaa, osu kẹwaa, ọdun ta a wa yii, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, ti fọkan awọn alatilẹyin rẹ balẹ pe ko ni i pẹ rara ti ẹgbẹ naa yoo fi gba iṣakoso ipinlẹ Ondo pada lọwọ Gomina Rotimi Akeredolu to n tukọ rẹ lọwọ.
Jẹgẹdẹ sọrọ idaniloju yii lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nigba ti wọn n ṣi olu-ile ẹgbẹ naa tuntun ti wọn sẹsẹ kọ dipo eyi tawọn janduku kan dana sun lasiko iwọde SARS to kọja.
O ni Akeredolu ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, iyẹn All Progressive Congress (APC) gan-an ti mọ pe nnkan ko ni i ṣẹnuure fawọn ninu igbẹjọ to n lọ lọwọ nile-ẹjọ to n gbọ awuyewuye to su yọ ninu eto idibo to wa l’Akurẹ.
Amofin agba ọhun ni o da oun loju daadaa pe orukọ oun nile-ẹjọ yoo kede gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa nitori pe awọn ẹri to wa niwaju igbimọ olugbẹjọ ẹlẹni mẹta naa too le Arakunrin kuro nile ijọba.
O gba gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ nimọran lati wa ni iṣọkan, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn asaaju titi ti oun ti wọn n foju sọna fun yoo fi tẹ wọn lọwọ.