Awọn eto ọrọ aje ta a n ṣe atunṣe rẹ ti bẹrẹ si i so eeso rere –Aarẹ Tinubu

Adewale adeoye

‘‘Bi ẹkun ba dalẹ ni, ayọ ati ireti ọtun n bọ lowurọ, diẹ lo ku, gbogbo ọmọ orileede Naijiria pata ni wọn maa jẹ gbadun’’. Eyi lọrọ ti olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, fi ranṣẹ sawọn ọmọ orileede yii nibi eto pataki kan ti wọn fiwe pe e si laipẹ yii.

Gẹgẹ bo ṣe wi, Aarẹ Tinubu ni oun mọ daju pe nnkan ko fara rọ laarin ilu, paapaa ju lọ fawọn mẹkunu, ṣugbọn o ṣe pataki foun lati ṣe awọn atunto gbogbo toun n ṣe seto ọrọ aje orileede yii, nitori kawọn araalu le gbadun lọjọ iwaju ni.

Nibi eto ikẹkọọ-gboye awọn akẹkọọ ileewe giga Federal University of Technology, Akure, (FUTA), to waye laipẹ yii ni Aarẹ Tinubu ti sọrọ ọhun di mimọ.

Ọga agba ileewe fasiti ‘Ilọrin (University of Ilorin), Ọjọgbọn Wahab Ẹgbẹwọle, to ṣoju Aarẹ Tinubu nibi eto pataki ọhun jiṣẹ rẹ fawọn alejo pataki gbogbo ti wọn wa lori ijokoo lọjọ naa pe ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu rẹ lori awọn atunṣẹ kọọkan to n ṣe lọwọ nipa eto ọrọ-aje orileede yii.

Ninu iwe apilẹkọ ti Ọjọgbọn Wahab ka lorukọ Tinubu setiigbọ awọn alejo naa lo ti sọ pe, ‘‘Awọn atunṣe kọọkan ti mo n ṣe lọwọ nipa eto ọrọ-aje orileede yii le maa mu inira nla ba awọn araalu, ṣugbọn mo fẹẹ fi da yin loju pe fun igba diẹ ni, awọn eto wa ti n so eeso rere lọwọ, laipẹ lawọn araalu yoo bẹrẹ si i gbadun gidi.

‘’Mo fẹẹ sọ fun yin pe o ṣe pataki pupọ fun wa gẹgẹ bii olori to ni afojusun gidi lati gbe igbese gidi ta a gbe yẹn. Nigba ta a maa fi wọle sipo aṣẹ orileede yii, nnkan ti bajẹ kọja afẹnusọ la ṣe gbe igbesẹ ta a gbe yẹn. Tẹlẹ, a kan maa n lọọ ko awọn ohun gbogbo ta a n jẹ wọle lati Oke-Okun ni, ṣugbọn ni bayii, nnkan ti yatọ gidi, awa naa ti n ṣe awọn nnkan ti ẹnu n jẹ sita. ‘’Mi o binu bi awọn alatako ba sọrọ odi sijọba mi. Ohun to jẹ mi logun ju lọ ni bi ọjọ iwaju awọn ọmọ Naijiria ṣe maa daa, ti a si maa bọ loko ẹru laipẹ. Gbogbo ilakaka awọn araalu pata ni mo n ri, bẹẹ ni ko sohun kankan to ṣokunkun sijọba mi pe ebi ati iyan wa nita, ṣugbọn mo fi da yin loju pe o maa too dopin laipẹ yii.

‘’Ko wu ijọba mi lati fiya to pọ to yii jẹ araalu rara, ṣugbọn a gbọdọ ṣe awọn nnkan to maa pada waa so eeso rere nigbẹyin ni. Lagbara Ọlọrun Ọba, gbogbo idile lorileede yii lo maa pada rẹrin-in ayọ nigba ta a ba pari awọn akọ iṣẹ ta a n ṣe lọwọ lori eto ọrọ-aje orileede yii.

Ju gbogbo rẹ lọ, a n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu lati ri i pe eto aabo fẹsẹ mulẹ daadaa laarin ilu, o si da mi loju daadaa pe awọn agbofinro wa to gbangbaa sun lọyẹ, apa wọn maa too ka awọn ọbayejẹ ẹda gbogbo ti wọn n da omi alaafia orileede yii ru. Gbogbo wọn pata ni wọn maa kabaamọ ohun ti wọn n ṣe.

Leave a Reply