Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn ajinigbe tun ṣoro nipinlẹ Ọyọ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun (19), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, nigba ti wọn ji Pasitọ ìjọ Ridiimu kan, Oluṣọ-agutan Olugbenga Ọlawore, pẹlu awọn mẹtala mi-in gbe lọ.
Pasitọ Ọlawore, alakooso ṣọọṣi ti wọn n pe ni Heavens Gate Parish, Redeemed Christian Church of God, iyẹn, ẹka ijọ Ridiimu, to wa lọna Agbara si Lusada, nipinlẹ Ogun, ni wọn ji gbe pẹlu awọn ero mẹtala yooku ti wọn jọ wa ninu bọọsi kan naa.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, laipẹ yii ni pasitọ yii padanu iya ẹ, to n jẹ Diakoni Deborah Ọlawore.
Ọjọ Jimọ to n bọ yii, iyẹn Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu yii, ni wọn fi eto itẹ ẹyẹ oku si, ti aṣekagba ayẹyẹ isinku yoo si waye lọjọ Jimọ ti i ṣe Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ọdun yii.
Gbogbo eto ti wọn ti ṣe silẹ ree lati bii oṣu meji sẹyin. Bi wọn yoo si ṣe ri ayẹyẹ ọhun ṣe laṣeyọri ni Pasitọ Ọlawore ba lọ si ilu Ìpàpó, lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ.
Ọkọ bọọsi elero mẹrinla la gbọ pe ojiṣẹ Ọlọrun naa wọ nigba to n pada si Eko lẹyin to ti pari ohun to lọọ ṣe.
Ṣugbọn ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Jimọ yii, bi bọọsi naa ṣe de ibì kan laarin Lanlatẹ siluu Eruwa, nitosi Maya, lawọn janduku agbebọn yọ si wọn tibọn-tibọn lati inu igbo lojiji, ti wọn si fi ibọn dari ojiṣẹ Ọlọrun naa pẹlu awọn ero yooku ninu ọkọ naa lọ sinu aginju igbo.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti gbọ nipa ìṣẹlẹ yii, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Hamzat Adebọla, si ti gbe ikọ awọn atọpinpin kan jade laarin awọn agbofinro lati ṣiṣẹ lori bi wọn yoo ṣe ri awọn eeyan ti wọn ji gbe ọhun gba yọ lakata awọn ajinigbe naa.
A tun gbọ pe awọn ajinigbe naa ti kan si iyawo pasitọ yii lori aago, nnkan bii aago mẹjọ ni wọn pe e, wọn si ni ki pasitọ naa ba iyawo rẹ sọrọ, ibẹ lo ti sọ fun un pe miliọnu mẹwaa Naira (N10m) lawọn maa gba gẹgẹ bii owo itusilẹ ẹni ọwọ ọhun.
Laaarọ ọjọ keji, iyẹn ọjọ Satide yii, awọn agbebọn naa tun pe iyawo pasitọ, wọn si ni ko tun ba ọkọ rẹ sọrọ, ibẹ ni Pasitọ Ọlawore ti n parọwa siyawo rẹ pe ko wa gbogbo ọna, koda bo jẹ miliọnu kan Naira, ko wa a jade, ko ma jẹ ki wọn pa oun sinu igbo naa, tori wọn ti fi oku ati egungun awọn ti wọn ti pa ṣaaju latari airi owo itusilẹ san lasiko, han oun.
Laarin ọrọ naa lawọn agbebọn ti gba foonu lọwọ ọkọ rẹ, ti wọn si bẹrẹ si i fi ede Fulani sọrọ, eyi lo jẹ ki iyawo yii mọ pe Fulani lawọn ti wọn ji ọkọ oun atawọn ero ọkọ naa gbe.
Amọ nigba tobinrin yii beere pe ibo ni koun ti gbe owo naa pade wọn toun ba ti ri i, niṣe ni wọn pa foonu, latigba naa si ni ipe ko ti tun pada wọle sori nọmba ọhun mọ, bẹẹ lawọn agbebọn yii ko ti i pe pada.