Awọn Fulani lo ji mi gbe, ọpọlọpọ wakati ni wọn fi so mi mọlẹ bii ẹran-Imaamu Oyinlade

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Alaaji Ibrahim Bọdunde Oyinlade, Imaamu agba tilu Ùsò, nijọba ibilẹ Ọwọ, tawọn ajinigbe kan ki mọlẹ, ti wọn si ji gbe sa lọ ninu oko rẹ ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin sọrọ ilẹ kun, nigba to n ṣalaye iriri rẹ fun akọroyin wa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

Alaaji Bọdunde sọ ninu ọrọ rẹ pe iṣẹ loun n ṣe lọwọ ninu oko oun lọjọ iṣẹlẹ ọhun ti awọn meji kan fi deedee yọ si oun lojiji, ti wọn si fipa wọ oun wọnu igbo lọ.

O ni fun bii wakati mẹfa gbako lawọn fi rin ninu igbo titi ti wọn fi de ibi kan ti wọn tẹdo si, nibẹ lo ni wọn ti fi okun de oun lọwọ lẹsẹ, ti wọn si tun de oun mọlẹ bii ẹran.

O ni ori iso loun wa titi ilẹ ọjọ keji fi mọ nigba tawọn janduku méjèèjì ti wọn waa ji oun gbe wa ibi kan fẹgbẹ le ni tiwọn nibi ti wọn sun si.

Awọn ọdaran ọhun lo ni wọn ko ba oun sọ ohunkohun titi ti olori wọn fi waa ba awọn lọjọ keji, o ni nigba ti ọga wọn de ni wọn too kan si awọn ẹbi oun, ti wọn si jọ dunaa-dura si miliọnu meji Naira.

Alaaji Bọdunde ni ọrọ ti wọn n sọ loun fi mọ pe Fulani ni wọn, o ni awọn janduku ọhun mọ daadaa pe Imaamu agba loun ninu esin Musulumi. Bẹẹ ni wọn ti kọkọ kilọ foun pe awọn mọ oun daadaa, nitori ọjọ pẹ ti awọn ti n ṣọ oun, wọn ni owo lasan lawọn fẹẹ gba lọwọ oun, awọn ko ṣetan lati pa oun ti oun ba ti le fọwọsowọpọ pẹlu awọn.

Ni kete towo ti wọn beere fun ti tẹ wọn lọwọ lo ni wọn ti tu oun silẹ, ti wọn si waa da oun pada si itosi oko oun ti wọn ti kọkọ ji oun gbe.

Imaamu agba ọhun gbosuba fawọn agbofinro pẹlu igbesẹ ti wọn gbe lori bọwọ ṣe pada tẹ Muinah to jẹ ọga awọn to ji oun gbe.

O ni o pẹ tawọn Fulani darandaran ti n yọ awọn lẹnu ni Ùsò, ọọpọ awọn agbẹ lo ni wọn ko laya lati lọọ ṣiṣẹ ninu oko mọ nitori ibẹru awọn Fulani ajinigbe ti wọn n fi maaluu dida boju lasan.

Ojiṣẹ Ọlọrun ọhun parọwa s’ijọba ipinlẹ Ondo lati ko awọn Amọtẹkun atawọn ẹṣọ aabo mi-in wa si agbegbe awọn, ki ọkan awọn araalu tun le balẹ diẹ.

Awọn afurasi mẹta, Isah Bello, ẹni ogoji ọdun, ati ọmọ rẹ, Aisha Bello, ọmọ ogun ọdun, pẹlu Muinah Muhammed, ẹni ọdun mọkandinlogun, lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ lori iṣẹlẹ naa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nọmba Bello ni Muinah to jẹ ọga awọn ajinigbe naa fi pe awọn ẹbi Imaamu ti wọn ji gbe lati dunaa dura pẹlu wọn.

Nigba ti akọroyin wa fọrọ wa Bello lẹnu wo, o ni iṣẹ maaluu dida oun loun gbaju mọ l’Ọgbẹsẹ, n’ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, nibi ti oun fi ṣe ibugbe, o ni oun ko le sọ ni pato bi siimu foonu oun ṣe de ọwọ Muinah.

Aisha to jẹ ọmọ rẹ sọ ni tiẹ pe ibi kan naa loun ati Muinah tí n taja ninu ọja Ọgbẹsẹ, o ni laipẹ yii ni ọkunrin naa waa ba oun lati tọrọ siimu oun, ti oun si fun un laimọ pe iṣẹ ibi lo fẹẹ lọọ fi ṣe.

O ni lati bii ọjọ diẹ sẹyin loun ti n yọ ọmọkunrin naa lẹnu pe ko da siimu oun pada, ṣugbọn o kọ jalẹ, ko fun oun.

Aisha ni Muinah ki i ṣe ọrẹkunrin oun, bẹẹ ni ko si nnkan mi-in to tun pa awọn mejeeji pọ ju pe awọn jọ n taja nibi kan naa lọ.

O ni Muinah ti sọ fun oun lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ pe oun ko ni i jẹwọ fawọn ọlọpaa bo ti wu ki wọn fọrọ wa oun lẹnu wo to.

Ninu ọrọ ti Muinah ba akọroyin wa sọ, ṣe lo ṣẹ kanlẹ loootọ pe oun ko ri Alaaji Bọdunde ri laye oun.

O ni oun mọ Aisha ati baba rẹ loootọ, ṣugbọn oun ko ranti asiko ti oun gba siimu lọwọ eyikeyii ninu wọn.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori ọna lati ri awọn ẹgbẹ Muinah to sa lọ mu.

Bakan naa lo ni iwadii ni yoo sọ boya Bello ati Aisha to jẹ ọmọ rẹ mọ nipa iṣẹlẹ ọhun tabi bẹẹ kọ.

 

Leave a Reply