Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ileesẹ eto idajọ ipinlẹ Ondo ti wọ awọn Fulani mejidinlogun tọwọ tẹ lọsẹ to kọja pẹlu ibọn ati oriṣiiriṣii nnkan ija oloro mi-in lọ sile-ẹjọ Majisreeti Kin-in-ni to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, lori ẹsun mẹfa ọtọọtọ.
Orukọ awọn olujẹjọ ọhun ni, Abdularasak Idris, Rufai Nura, Sagri Musa, Imarana Bello, Tasiu Sulaiman, Musa Bala, Saliu Saidu, Musur Adamu, Nura Saidu, Salisu Usman, Aruna Tukur, Abdulai Ibrahim, Abubarka Aliu, Shuaibu Aliu, Imrana Yusuf, Mustafa Abdulahi, Mubarak Tsalha ati Hasan Sani.
Awọn Fulani ọhun ni wọn fẹsun gbigbimọ-pọ huwa to lodi sofin, biba ọpọlọpọ nnkan ija oloro nikaawọ wọn, eyi to da jinnijinni bo awọn araalu, ririn regberegbe laago meji oru, didi oṣiṣẹ Amọtẹkun lọwọ lẹnu iṣẹ wọn ati wiwa ọkọ niwakuwa pẹlu erongba lati ṣeku pa awọn oṣiṣẹ ẹsọ Amọtẹkun meji, Moses Adegbenro ati Sọji Adegbenro.
Agbẹjọro ijọba, Amofin O. F. Akeredolu, juwe awọn ẹsun naa bii ohun to lodi, to si tun ni ijiya to lagbara labẹ ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Akeredolu dabaa ki gbogbo awọn olujẹjọ naa ṣi wa lọgba ẹwọn titi tile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to gba adajọ nimọran.
Ninu ipinnu rẹ, Onidaajọ Musa Al-Yunnus fountẹ lu ohun ti agbefọba sọ pẹlu bo ṣe ni ki wọn si lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn na.
Adajọ ọhun paṣẹ fawọn olupẹjọ lati ri i daju pe wọn tete fi ojulowo awọn iwe ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ ṣọwọ sọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran.