Faith Adebọla
Titi dasiko yii lawọn araalu atawọn ọmọlẹbi Oloogbe Babarinde Mufutau, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta, ṣi n daro ẹni wọn, ti wọn si n beere fun idajọ ododo latari bi wọn ṣe lawọn Fulani darandaran kan lo ṣa baba agbalagba naa pa sọna oko ẹ lagbegbe Ibarapa, l’Ọjọruu, Wẹsidee to kọja yii. Ileeṣẹ ọlọpaa lawọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun.
Olori ẹgbẹ idagbasoke ilu Igangan (Igangan Development Advocates), Ọgbẹni Ọladokun Ọladiran, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ f’ALAROYE sọ pe lati aarọ ọjọ iṣẹlẹ naa ni oloogbe ọhun ti n ṣiṣẹ ninu oko paki rẹ, igba to dọwọ irọlẹ to ṣiwọ, to n dari re’le ẹ lawọn Fulani darandaran yọ jade si i, lorita ọna to lọ si Abule Konko, nitosi Ayetẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa.
O ni niṣe ni wọn fa ada ati ida to wa ninu apo to gbe kọpa yọ, ti wọn si bẹrẹ si i kun baba onibaba bii ẹran ileya. Wọn ni baba naa kigbe oro fun iranlọwọ, ṣugbọn ko rẹni gba a silẹ lọwọ awọn apaayan to ṣakọlu si i ọhun.
Lẹyin ti wọn ti ṣa a tẹrun ni wọn tuka lori baba naa, onikaluku wọn si ba ẹsẹ rẹ sọrọ. Inu agbara ẹjẹ ọhun ni baba naa dakẹ si, igba tawọn eeyan kan ti wọn fura si ohun to ṣẹlẹ fi maa de’bẹ, akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin, ni wọn ba gbe oku rẹ wale.
Ọladiran lawọn ti fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni teṣan wọn to wa niluu Ayetẹ, ṣugbọn wọn kan sọ pawọn gbọ ni, wọn o ṣe nnkan kan nipa rẹ.
ALAROYE ṣapa lati ba DPO teṣan Ayetẹ sọrọ, ṣugbọn ọkunrin naa ko gbe ipe, bẹẹ ni ko da atẹjiṣẹ ta a fi ranṣẹ si i pada.
Nigba ta a kan si Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adewale Ọṣunfẹṣọ, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti gbọ si i, ati pe iwadii ti n lọ lori ẹ, oun o si le ba wa sọrọ ju bẹẹ lọ.