Awọn Fulani ya wọ oko nla kan n’Ibadan, wọn ji ọmọ oloko gbe

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ere àsá-ṣubú-lébú lawọn oṣiṣẹ inu oko nla kan to wa lagbegbe Òkè-Ọ̀dàn, Ọlọ́mọ, lagbegbe Apẹtẹ, n’Ibadan sa lati bọ lọwọ ijinigbe tabi ikú ojiiji nigba ti awọn Fulani ajinigbe ya wọ inu oko ti wọn ti n ṣiṣẹ nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ ọjọ kejilelogun, oṣù kejì, odun 2021 yii, ti wọn si ji ọmọ oloko naa gbe.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, bi awọn ọdaran ẹlẹni mẹrin ọhun ṣe dé inu oko naa ni wọn yinbọn soke leralera lati dẹruba awọn oṣiṣẹ naa, ti wọn sì n pariwo pe “ẹni tó loko yii da”? Ẹni tó loko yii dà”?

Kò sí ẹni tó dúró dè ẹnikan ti awọn oṣiṣẹ naa fi sa àsálà fún ẹ̀mí ara wọn.

Bo tilẹ jẹ pé wọn kò rí olókó nitori baba naa ko sí nibẹ lasiko naa, wọn padà ji ọmọkùnrin rẹ̀ to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun gbe.

Awọn to n ṣiṣẹ lọwọ nínú ọkọ naa lasiko iṣẹlẹ ọhun fìdí ẹ mulẹ pe Fúlàní lawọn ọdaran naa.

Lẹyin ti wọn fi iṣẹlẹ ọhun tó awọn agbofinro leti, DPO, ìyẹn ọga ọlọpaa teṣan Apẹtẹ, n’Ibadan, funra rẹ lo ko àwọn ọlọ́pàá sodi lọ sí gbogbo inu igbó to wa layiika oko ti awọn Fúlàní naa ti ṣọṣẹ́. Ṣugbọn akitiyan wọn kò ti i seso rere titi ta a fi parí akojọ iroyin yii.

Ìgbìyànjú ALAROYE lati gbọ tenu CSP Olugbenga Fadeyi ti i ṣe agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ìpínlẹ Ọyọ lori iṣẹlẹ yii ko seso rere pẹlú bi akọroyin wa ṣe pé e lọpọlọpọ igba, ṣugbọn ti ko gbe èyíkéyìí ninu awọn ipe naa.

Leave a Reply