Awọn gomina ẹgbẹ PDP marun-un (G-5) wọle ipade l’Ekoo

Faith Adebọla

Ba a ṣe n kọ iroyin yii, ipade pataki kan n lọ lọwọ laarin awọn gomina ipinlẹ marun-un kan lati inu ẹgbẹ PDP ti wọn n jẹ (G-5) ti wọn ya ara wọn sọtọ pe awọn ko ni i ba oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, ṣe ti ko ba yọ alaga ẹgbẹ naa, Iyourchi Ayu, ko si fi ẹlomi-in to wa lati iha Guusu si i gẹgẹ bii adehun ti wọn jọ ṣe.

Awọn gomina ọhun ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ti ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, Gomina  ipinlẹ Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi ati Gomina ipinlẹ Abia, Victor Ikpeazu. Awọn eeyan wọnyi ni wọn ti n yẹra fun ipolongo ibo oludije wọn funpo aarẹ wọn, ti wọn ni awọn ko ni i ni nnkan kan an ba a ṣe nitori ko tẹle adehun ti awọn jọ ṣe pe ti oludije funpo aarẹ ba ti wa lati Ariwa, lati Guusu ni alaga yoo ti wa, bẹẹ ni Ayu ṣeleri pe bi ọrọ ba ri bẹẹ, oun yoo fi ipo oun silẹ. Ṣugbọn ti ọkunrin naa kọ lati ṣe bẹẹ.

Otẹẹli Southern Sun, iyẹn (Ikoyi Hotel), atijọ ni ipade naa ti n waye.

Awọn gomina maraarun yii atawọn agbaagba ẹgbẹ mi-in ni wọn peju sibi ipade to ṣi n lọ lọwọ naa, nibi ti wọn ti fẹẹ fi ipinnu wọn han lori eto idibo ọdun to n bọ ati igbesẹ to ṣee ṣe ki wọn gbe lori rẹ.

Leave a Reply