Awọn gomina ilẹ Hausa ti gba pe ki oludije funpo aarẹ APC wa lati iha Guusu

Ọrẹoluwa Adedeji

Awọn gomina to wa lati ilẹ Hausa atawọn aṣaaju wọn kan lati agbegbe naa ti fọwọ si i pe ki oludije sipo aarẹ ọdun to n bọ lorukọ ẹgbẹ APC wa lati apa Guusu ilẹ wa.
Ninu iwe kan ti awọn gomina naa fọwọ si to tẹ ALAROYE lọwọ ni wọn ti ṣọ pe, ‘‘Lẹyin ifikunlukun, a n sọ ipinnu wa di mimọ pe lẹyin ọdun mẹjọ ti Aarẹ Buhari ba lo nipo gẹgẹ bii aarẹ, ẹni ti yoo du ipo aarẹ lọdun 2023, gbọdọ jẹ ọkan ninu wa ti yoo wa lati apa iha Guusu. O jẹ ohun to tọna, ti yoo si pọn ẹgbẹ APC le, o jẹ ojuṣe to yẹ, ti ko si ni ohunkohun i ṣe pẹlu ipinnu tabi igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu mi-in ba gbe lori eleyii. A n fi idi rẹ mulẹ pe gbigbe iru igbesẹ bayii ni i ṣe pẹlu ṣiṣe agbekalẹ ẹgbẹ ti yoo duro deede, ti yoo wa ni iṣọkan ati itẹsiwaju.
‘‘Nidii eyi la fi n gba Aarẹ Buhari nimọran pe wiwa ẹni ti yoo rọpo rẹ gẹgẹ bii aarẹ lọdun to n bọ gbọdọ wa lati ọdọ awọn eeyan wa ni apa Guusu nikan. A fi asiko yii rọ awọn eeyan wa ti wọn wa lati apa Ariwa ti wọn jẹ oludije lati jawọ ninu didupo naa ni ifẹ orileede yii, ki wọn si jẹ ki awọn eeyan wa to wa lati Guusu nikan dije fun ipo yii lasiko idibo abẹle wa. A mọ riri akitiyan ọkan ninu wa, Gomina Abubakar Badaru, to gba lati jawọ ninu didu ipo aarẹ.
‘‘Ojuṣe ẹgbẹ oṣelu APC ni lati ri i pe wọn ṣe agbekalẹ eto idibo ti yoo mu agbega ba orileede yii, ati lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe ọna ijọba awa-ara-wa lati gba isakoso ijọba ṣi wa, paapaa fun awọn ti wọn mọ riri ifọwọsowọpọ ati ṣiṣe agbekalẹ orileede to fẹsẹ mulẹ. Akoko yii jẹ asiko ironu gidi, ati lati ri i pe a gba ọna to dara, ti gbogbo ẹgbẹ fọwọ si, lati yan aṣoju ẹgbẹ wa, a si rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati ṣe ojuṣe wọn ni agbọn yii.’’
Awọn gomina ipinlẹ Katsina, Niger, Nasarawa, Borno, Gombe, Kaduna, Zamfara, Plateau, Sokoto, Kano ati Kebbi lo fọwọ si atẹjade naa.
Pẹlu igbesẹ yii, ohun to tumọ si bayii ni pe awọn oludije lati ilẹ Yoruba, Ibo ati Ijaw nikan ni yoo kopa ninu eto idibo abẹle APC ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii

Leave a Reply