Awọn gomina marun-un ko yọju sibi ipolongo ibo Atiku ni Uyo

Monisọla Saka

Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni ẹgbẹ oṣelu PDP bẹrẹ eto ipolongo ibo wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe ifilọlẹ rẹ niluu Uyo, olu ilu ipinlẹ Akwa Ibom. Ni papa iṣere nla Nest of Champions ni ifilọlẹ eto ipolongo ibo gbogboogbo ọdun to n bọ ti ko ju bii oṣu mẹrin ti wọn yoo di i lọ naa ti waye. Ṣe ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023, ni wọn yoo dibo aarẹ nilẹ yii.

Bi gbogbo awọn eekan lẹgbẹ oṣelu PDP ṣe tuyaaya tuyaaya jade lasiko ti Atiku n ṣeleri lati gba ilẹ Naijiria silẹ lọwọ eto aabo ti to ti dẹnu kọlẹ, eto ọrọ aje ti ko rajaja, ati lati mu ki iṣọkan wa lapa Ariwa ati Guusu ilẹ yii lawọn marun-un kan ti wọn jẹ gomina lẹgbẹ oṣelu naa o ba wọn debẹ, depo pe wọn yoo ba wọn kopa ninu eto ọhun. Awọn gomina ipinlẹ maraarun yii ni, Gomina Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers, Samuel Ortom ti ipinlẹ Benue, Okezie Ikpeazu to jẹ gomina ipinlẹ Abia, gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ati Ifeanyi Ugwunayi, ti ipinlẹ Enugu.

Tẹ o ba gbagbe, awọn gomina maraarun yii ni wọn ti yọ ara wọn kuro ninu igbimọ eto ipolongo ẹgbẹ ọhun lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti kọ lati mu ileri wọn ṣẹ lori yiyọ ti wọn ni ki wọn yọ Iyorchia Ayu gẹgẹ bii alaga apapọ ẹgbẹ naa.

Lara awọn ti wọn peju-pesẹ sibi ifilọlẹ eto ipolongo aarẹ lẹgbẹ PDP ni, oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu ọhun funra rẹ, Atiku Abubakar, Dokita Ifeanyi Okowa ti yoo ṣe igbakeji fun un, Alaga apapọ ẹgbẹ naa, Dokita Iyorchia Ayu, awọn wọnyi ni wọn ko awọn jankan jankan, titi kan awọn alatilẹyin atawọn igbimọ amuṣẹṣe lẹgbẹ naa (NWC), sodi nibi ayẹyẹ ọhun.

Ki eto too bẹrẹ ni wọn ti kọkọ lọọ yọju sawọn ori ade nipinlẹ Akwa Ibom, paapaa ju lọ,  Ọba Nteyin Solomon Etuk, ti i ṣe ọba ilu Nsit Ubium, to si tun jẹ alaga gbogbogboo fun igbimọ lọbalọba jake-jado ipinlẹ naa.

Lara awọn eeyan pataki mi-in ti wọn tun wa nibi ayẹyẹ naa ni igbakeji Aarẹ tẹlẹri, Namadi Sambo, awọn olori ileegbimọ aṣofin tẹlẹ, David Mark, Bukọla Saraki, ati Anyim Pius Anyim. Bakan naa ni awọn alaga lẹgbẹ naa tẹlẹ, Oloye Okwesilieze Nwodo, Alaaji Adamu Muazu ati Uche Secondus wa nibẹ pẹlu.

Mẹrin ninu awọn gomina apa Guusu Guusu naa wa nikalẹ pẹlu alaga igbimọ awọn gomina to tun jẹ gomina ipinlẹ Sokoto, Alaaji Aminu Tambuwal.

Leave a Reply