Faith Adebọla, Eko
Agbarijọ awọn gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu alatako, Peoples Democratic Party (PDP), ti kegbajare sijọba ataraalu pe afaimọ ki odo gbese ti a n luwẹẹ ninu rẹ lasiko yii ma gbe orileede naa mi, wọn ni ẹyawo ti Naijiria n ṣe lasiko yii ti kọja aala.
Atẹjade kan tawọn gomina naa fi lede lẹyin ipade wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, niluu Uyo, nipinlẹ Akwa Ibom, nibi ti wọn ti jiroro ipo ti ọrọ-aje orileede yii wa, ni wọn ti figbe bọnu bẹẹ.
Wọn ni bi ijọba apapọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari n tukọ rẹ lọwọ yii ṣe n ya owo lọwọ taja tẹran kari aye kọ awọn lominu gidi, tori ọpọ awọn ẹyawo naa ko nitumọ, ko si ye awọn bi wọn ṣe n na an.
Wọn ni gbese to wa lọrun Naijiria bayii ti ga gegere, o ti ju tiriliọnu lọna mẹrindinlogoji naira (#36 trilliọn) lọ, iyẹn ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun lọna mẹrindinlọgbọn naira.
Awọn gomina naa ni o maa ṣoro fun orileede to ṣẹṣẹ n goke agba bii tiwa yii lati bọ ajaga gbese to pọ bẹẹ kuro lọrun bọrọ, wọn ni bii igba ti ijọba to wa lode yii fẹẹ da wa pada soko ẹru lẹẹkeji ni, tori gbogbo okoowo ati ọrọ-aje lo maa dẹnu kọlẹ bi nnkan ṣe n lọ yii.
Awọn gomina naa fẹsun kan ijọba pe nnkan bii ida ọgọrin ninu ọgọrun-un owo ti wọn n ya sọtọ lọdọọdun lo jẹ pe ele ori gbese lasan ni wọn n na an si, ti gbese gọbọi naa si wa nibẹ lai yingin.
Wọn ni o ba ni ninu jẹ pe gbogbo anfaani ti iṣejọba Aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, mu wa, pẹlu bi baba naa ṣe yọ okun gbese kuro lọrun orileede wa ni iṣakoso to wa lode yii ti sọ nu, ti wọn si ti jẹ ki orileede naa maa luwẹẹ ninu alagbalugbu odo gbese rẹpẹtẹ.
Wọn ni lara awọn ibi ti ijọba n nawo ti wọn ya si ni ileeṣẹ tẹlifiṣan ijọba apapọ, Nigeria Television Authority (NTA) eyi ti wọn ti sọ di ọpa ti wọn fi n gbọn owo ilu danu lọdọọdun.
Wọn tun bẹnu atẹ lu ọna ti banki apapọ ilẹ wa, CBN, gba n mojuto eto iṣunna owo, wọn ni Central Bank of Nigeria naa ti sọ ara rẹ di ijọba kan lọtọ to jẹ yala yolo bo ṣe wu wọn ni wọn n ṣe lori ọrọ ẹyawo ati inawo.
Awọn gomina naa ni ko yẹ kijọba maa yawo lai si ete ati eto pataki to gunmọ kan ti wọn fẹẹ na iru owo bẹẹ le lori, ko si yẹ ki wọn na iru owo bẹẹ sori nnkan mi-in, tabi sori awọn nnkan ti ko ni i pawo wọle, tabi ki wọn maa yawo lati sanwo-oṣu awọn oṣiṣẹ.
Wọn dabaa pe ki banki apapọ ṣiṣẹ lori bi owo naira ṣe n di yẹbuyẹbu lojoojumọ, ti agbara rẹ ni ọja okoowo agbaye n dinku nigba gbogbo, ki wọn si jẹ ki owo naa lagbara si i.
Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Emmanuel Udom, to gba awọn ẹlẹgbẹ rẹ lalejo wa nipade naa. Bakan naa ni alaga awọn gomina labẹ asia PDP, Aminu Tambuwal tipinlẹ Sokoto naa wa nipade naa. Awọn gomina to ku ni Okezie Ikpeazu tipinlẹ Abia, Duoye Diri tipinlẹ Bayelsa, Samuel Ortom lati ipinlẹ Benue, Ifeanyi Okowa lati Delta ati Ifeanyi Ugwuanyi tipinlẹ Enugu.
Bakan naa ni gomina Nyesom Wike tipinlẹ Rivers, Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ, Ahmadu Fintiri lati Adamawa, Godwin Obaseki ti ipinlẹ Edo, Bala Mohammed ti Bauchi, Darius Ishaku lati Taraba and Igbakeji gomina ipinlẹ Zamfara, Mahdi Mohammed pesẹ sipade ọhun.
Awọn gomina naa tun mẹnu ba bijọba apapọ ṣe lawọn fofin de ikanni ibanisọrọpọ ori atẹ ayelujara ti Tuita, wọn lawọn ko fara mọ igbesẹ naa rara, kijọba jawọ ninu igbesẹ yii, tori ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ ni awọn ka ọrọ tijọba n sọ si.
Wọn ni bijọba ṣe gbe igbesẹ naa ko yatọ si ti olori to fẹẹ sọ ara rẹ di apaṣẹ waa, tabi ti ijọba ologun, eyi ko si ba ilana ijọba awa-ara-wa ti Naijiria n lo mu. Wọn ni ko si nnkan to ni kileeṣẹ Tuita ma yọ ọrọ ti Aarẹ tabi ẹnikẹni ba kọ sori ikanni wọn danu tiru ọrọ bẹẹ ba ti tako ilana ijumọsọrọ ti wọn fi lelẹ fun lilo ikanni wọn.
Lori iṣoro eto aabo to dẹnu kọlẹ kaakiri orileede yii, awọn gomina naa bẹnu atẹ lu bawọn janduku kan ṣe n ṣakọlu sawọn ọlọpaa, ti wọn si n dana sun awọn ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ijọba ati awọn ọfiisi ajọ eleto idibo, INEC, kaakiri orileede yii.
Wọn gba ijọba apapọ niyanju lati tete ṣiṣẹ lori ofin ilẹ wa ti yoo yọnda fun idasilẹ ọlọpaa agbegbe, ọlọpaa ipinlẹ, ati ọlọpaa ibilẹ, wọn niru ofin bẹẹ ki i ṣe eyi tijọba gbọdọ fakoko ṣofo lori rẹ rara.
Bakan naa ni wọn rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati tubọ fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn ẹṣọ eleto aabo tawọn ipinlẹ ati agbegbe kan ti da silẹ, ki wọn le ro eto aabo lagbara kaakiri agbegbe.