Faith Adebọla
Amofin agba, Muiz Banirẹ, ti fẹsun kan awọn gomina ti wọn n ta ko gbedeke ọjọ tijọba apapọ ni nina owo Naira atijọ, iyẹn igba Naira, ẹẹdẹgbẹta Naira ati ẹgbẹrun kan Naira, eyi tijọba ti pa laro tuntun bayii, pe ko sidii meji tawọn gomina yii fi ta ku ju ki wọn le ri owo ra ibo lasiko eto idibo to wọle de tan yii ni.
Banirẹ, ẹni to ti figba kan jẹ kọmiṣanna feto ayika nipinlẹ Eko, sọ pe gbogbo ilakaka awọn gomina kan ti wọn ta ko bijọba ṣe fẹẹ ko owo atijọ naa nilẹ ki i ṣe nitori ifẹ ti wọn ni saraalu, amọ ki wọn ba le raaye na obitibiti owo atijọ ti wọn ti ji ko pamọ ni wọn ṣe n fariga lori ọrọ naa.
Lori ikanni LinkedIn rẹ, ajafẹtọọ-ọmọniyan ọhun sọ lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji yii pe: “Ọpọ ninu wa ni ko loye idi tawọn gomina kan fi n rakaka pe owo atijọ ṣi wulo, awọn araalu si gbọdọ maa na an lọdọ tawọn. Dajudaju, ki i ṣe pe awọn gomina yii ko mọ pe awọn ko laṣẹ lati kede owo taraalu maa na tabi eyi taraalu ko gbọdọ na, bẹẹ ni ki i ṣe pe wọn ko mọ pe awọn ko lagbara lati fidi aṣẹ ile-ẹjọ giga ju lọ mulẹ, wọn mọ daadaa pe o nibi tagbara ati aṣẹ awọn mọ, gbogbo eyi ti wọn n ṣe yii ko si labẹ aṣẹ wọn.
Amọ, aṣiri to wa nibẹ ni pe wọn fẹẹ tan awọn araalu ti ko ba fura, lati gba owo atijọ ti wọn ti ko pamọ tori ati ra ibo, ki wọn le fowo naa ra ẹri-ọkan awọn oludibo ni.
“Ẹyin oludibo, tawọn oloṣelu ba fẹẹ kowo fun yin, tabi tẹ ẹ fẹẹ gbowo lọwọ awọn oloṣelu, ẹ sọ fun wọn pe owo tutun ti banki apapọ ni ka maa na lẹ fẹ, amọran mi niyẹn.
“Owo ti banki apapọ ko ba ka si nina, ti banki apapọ ba pe e lowo atijọ, gomina kan o lagbara lati paṣẹ nina ẹ, aṣẹ ti ko nitumọ ni, ẹtan lo wa nidii ẹ.”
Bẹẹ ni Muiz Banirẹ sọ o.
Tẹ o ba gbagbe, lara awọn gomina to ti kede pe ni tawọn o, awọn ko fara mọ gbedeke ti ijọba apapọ ati banki agba ilẹ wa fi lede lori asiko ti nina owo atijọ naa yoo kasẹ nilẹ ni: Gomina Nasir El-Rufai ti ipinlẹ Kaduna, Babajide Sanwo-Olu ti Eko, Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun, Abdullahi Ganduje ti ipinlẹ Kano, Yahaya Bello ti Kogi, Bello Matawale ti Zamfara, Aminu Tambuwal ti Sokoto, atawọn mi-in.
Awọn kan lara wọn ti paṣẹ fawọn olugbe ipinlẹ wọn pe ki wọn ṣi maa na gbogbo owo atijọ naa lọ, wọn lawọn maa fiya jẹ ileeṣẹ okoowo tabi banki to ba kọ lati gba awọn owo naa, bo tilẹ jẹ pe Aarẹ ilẹ wa, Mohammadu Buhari, ti kede pe lati ọjọ kẹwaa, oṣu Keji yii, nijọba ti fopin si nina ẹẹdẹgbẹta Naira atijọ (N500) ati ẹgbẹrun kan Naira atijọ (N1,000), ti nina igba Naira (N200) yoo si tẹsiwaju di ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin.