Awọn Hausa atawọn ọmọọta n ja l’Oṣogbo o

Ija kan teeyan ko ti i gbọ hulẹhulẹ ohun to fa a gan-an bẹ silẹ laarin awọn Hausa oniṣowo kan ati awọn ọmọọta kan lagbegbe  Sabo l’Ọṣogbo, ipinlẹ Ọṣun, laaarọ yii. Ọkunrin kan ti wọn n pe ni “Ikẹja” lo ṣaaju awọn ọmọọta naa,  ti wọn si koju awọn mọla ọlọja to wa ni Saabo.

Ọpọ awon eeyan ni wọn ni wọn ti fara pa bayii, ṣugbọn iroyin ko ti i sọ pe ẹnikeni ku nibẹ. Awọn ọlọpaa adigboluja, ti wọn di ihamọra ogun, ti n rọ lọ sọna ibẹ, o si daju pe apa wọn yoo ka ohun yoowu ko jẹ.

 

Leave a Reply